Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 44:24-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Jeremiah sọ pẹlu fun gbogbo awọn enia, ati fun gbogbo awọn obinrin na pe, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa gbogbo Juda ti o wà ni ilẹ Egipti:

25. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli sọ, wipe, Ẹnyin ati awọn aya nyin, ẹnyin fi ẹnu nyin sọ̀rọ, ẹ si fi ọwọ nyin mu ṣẹ, ẹ si wipe, lõtọ awa o san ẹ̀jẹ́ wa ti awa ti jẹ, lati sun turari fun ayaba ọrun, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, njẹ ni pipamọ, ẹ pa ẹ̀jẹ́ nyin mọ, ati ni sisan ẹ san ẹ̀jẹ́ nyin.

26. Nitorina ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, gbogbo Juda ti ngbe ilẹ Egipti, sa wò o, emi ti fi orukọ nlanla mi bura, li Oluwa wi, pé, a kì yio pè orukọ mi li ẹnu ọkunrin-kunrin Juda ni gbogbo ilẹ Egipti, wipe, Oluwa, Ọlọrun wà.

27. Wò o, emi o ṣọ wọn fun ibi, kì si iṣe fun rere: ati gbogbo awọn ọkunrin Juda ti o wà ni ilẹ Egipti ni a o run nipa idà, ati nipa ìyan, titi nwọn o fi tan.

28. Ati awọn ti o sala lọwọ idà, yio pada ni iye diẹ lati ilẹ Egipti si ilẹ Juda; ati gbogbo iyokù Juda, ti o lọ si ilẹ Egipti lati ṣatipo nibẹ, yio mọ̀ ọ̀rọ tani yio duro, temi, tabi ti wọn.

29. Eyi ni yio si jẹ àmi fun nyin, li Oluwa wi, pe, emi o jẹ nyin niya ni ibiyi, ki ẹnyin le mọ̀ pe: ọ̀rọ mi yio duro dajudaju si nyin fun ibi:

30. Bayi li Oluwa wi; wò o, emi o fi Farao-hofra, ọba Egipti, le ọwọ awọn ọta rẹ̀, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi rẹ̀; gẹgẹ bi emi ti fi Sedekiah, ọba Juda, le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli ọta rẹ̀, ti o si wá ẹmi rẹ̀.

Ka pipe ipin Jer 44