Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 38:17-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Nigbana ni Jeremiah sọ fun Sedekiah pe; Bayi li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe: Bi iwọ o ba jade nitõtọ tọ̀ awọn ijoye ọba Babeli lọ, nigbana ni ọkàn rẹ yio yè, a ki yio si fi iná kun ilu yi; iwọ o si yè ati ile rẹ.

18. Ṣugbọn bi iwọ kì yio ba jade tọ awọn ijoye ọba Babeli lọ, nigbana ni a o fi ilu yi le ọwọ awọn ara Kaldea, nwọn o si fi iná kun u, iwọ kì yio si sala kuro li ọwọ wọn.

19. Sedekiah ọba, si sọ fun Jeremiah pe, Ẹ̀ru awọn ara Juda ti o ya tọ awọn ara Kaldea mbà mi, ki nwọn ki o má ba fi mi le wọn lọwọ; nwọn a si fi mi ṣẹsin.

20. Ṣugbọn Jeremiah wipe, nwọn kì yio si fi ọ le wọn lọwọ, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa ti mo sọ fun ọ: yio si dara fun ọ, ọkàn rẹ yio si yè.

21. Ṣugbọn bi iwọ ba kọ̀ lati jade lọ, eyi li ohun ti Oluwa ti fi hàn mi:

22. Si wò o, gbogbo awọn obinrin ti o kù ni ile ọba Juda li a o mu tọ̀ awọn ijoye ọba Babeli lọ, awọn obinrin wọnyi yio si wipe, Awọn ọrẹ rẹ ti tàn ọ jẹ, nwọn si ti bori rẹ: ẹsẹ rẹ̀ rì sinu ẹrẹ̀ wayi, nwọn pa ẹhin dà.

23. Nwọn o si mu gbogbo awọn aya rẹ ati awọn ọmọ rẹ jade tọ awọn ara Kaldea lọ: iwọ kì yio si sala kuro li ọwọ wọn, ọwọ ọba Babeli yio si mu ọ: iwọ o si mu ki nwọn ki o fi iná kun ilu yi.

24. Sedekiah si wi fun Jeremiah pe, Máṣe jẹ ki ẹnikan mọ̀ niti ọ̀rọ wọnyi, ki iwọ má ba kú.

25. Ṣugbọn bi awọn ijoye ba gbọ́ pe emi ti ba ọ sọ̀rọ, bi nwọn ba si wá sọdọ rẹ, ti nwọn sọ fun ọ pe, Sọ fun wa nisisiyi eyi ti iwọ ti sọ fun ọba, máṣe fi pamọ fun wa, awa kì o si pa ọ; ati eyi ti ọba sọ fun ọ pẹlu:

26. Nigbana ni ki iwọ ki o wi fun wọn pe, Emi mu ẹ̀bẹ mi wá siwaju ọba, pe ki o má mu mi pada lọ si ile Jonatani, lati kú sibẹ.

27. Gbogbo awọn ijoye si tọ̀ Jeremiah wá, nwọn bi i lere: o si sọ fun wọn gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi ti ọba ti palaṣẹ fun u. Bẹ̃ni nwọn dakẹ nwọn si jọ̃rẹ̀; nitori ẹnikan kò gbọ́ ọ̀ran na.

28. Jeremiah si ngbe agbala ile-túbu titi di ọjọ ti a kó Jerusalemu.

Ka pipe ipin Jer 38