Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 34:4-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Sibẹ, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, iwọ Sedekiah, ọba Juda: Bayi li Oluwa wi niti rẹ, Iwọ kì yio ti ipa idà kú.

5. Iwọ o kú li alafia: ati bi ijona-isinkú awọn baba rẹ, awọn ọba igbãni ti o wà ṣaju rẹ, bẹ̃ni nwọn o si ṣe ijona-isinkú fun ọ, nwọn o si pohunrere rẹ, pe, Yẽ oluwa! nitori eyi li ọ̀rọ ti emi ti sọ, li Oluwa wi.

6. Jeremiah woli, si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun Sedekiah, ọba Juda ni Jerusalemu.

7. Ni wakati na ogun ọba Babeli mba Jerusalemu jà, ati gbogbo ilu Juda ti o kù, Lakiṣi, ati Aseka: wọnyi li o kù ninu ilu Juda, nitori nwọn jẹ ilu olodi.

8. Ọ̀rọ ti o tọ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa lẹhin ti Sedekiah, ọba, ti ba gbogbo enia ti o wà ni Jerusalemu dá majẹmu, lati kede omnira fun wọn.

9. Pe, ki olukuluku enia le jẹ ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku enia, iranṣẹbinrin rẹ̀, ti iṣe ọkunrin Heberu tabi obinrin Heberu, lọ lọfẹ; ki ẹnikẹni ki o má mu ara Juda, arakunrin rẹ̀, sìn.

10. Njẹ nigbati gbogbo awọn ijoye, ati gbogbo enia, ti nwọn dá majẹmu yi, gbọ́ pe ki olukuluku ki o jẹ ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku, iranṣẹbinrin rẹ̀, lọ lọfẹ, ki ẹnikan má mu wọn sin wọn mọ, nwọn gbọ́, nwọn si jọ̃ wọn lọwọ.

11. Ṣugbọn lẹhin na nwọn yi ọkàn pada, nwọn si mu ki awọn iranṣẹkunrin ati awọn iranṣẹbinrin, awọn ẹniti nwọn ti jẹ ki o lọ lọfẹ, ki o pada, nwọn si mu wọn sin bi iranṣẹkunrin ati bi iranṣẹbinrin.

12. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa, wipe,

13. Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli, wi, pe; Emi ba awọn baba nyin dá majẹmu li ọjọ ti emi mu wọn jade lati ilẹ Egipti, kuro ninu oko-ẹrú, wipe,

14. Li opin ọdọdun meje ki olukuluku enia jẹ ki arakunrin rẹ̀ ki o lọ, ani ara Heberu ti o ta ara rẹ̀ fun ọ; yio si sìn ọ li ọdun mẹfa, nigbana ni iwọ o jẹ ki o lọ lọfẹ lọdọ rẹ: ṣugbọn awọn baba nyin kò gbọ́ temi, bẹ̃ni wọn ko tẹti wọn silẹ.

Ka pipe ipin Jer 34