Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 31:4-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Emi o tun ọ kọ́, iwọ o si di kikọ, iwọ wundia Israeli! iwọ o si fi timbreli rẹ ṣe ara rẹ lọṣọ, iwọ o si jade lọ ni ọwọ́-ijo ti awọn ti nyọ̀.

5. Iwọ o gbìn ọgba-ajara sori oke Samaria: awọn àgbẹ yio gbìn i, nwọn o si jẹ ẹ.

6. Nitori ọjọ na ni eyi, ti awọn oluṣọ lori oke Efraimu yio kigbe pe, Ẹ dide, ẹ si jẹ ki a goke lọ si Sioni sọdọ Oluwa, Ọlọrun wa.

7. Nitori bayi li Oluwa wi; ẹ fi ayọ̀ kọrin didùn fun Jakobu, ẹ si ho niti olori awọn orilẹ-ède: ẹ kede! ẹ yìn, ki ẹ si wipe: Oluwa, gbà awọn enia rẹ la, iyokù Israeli!

8. Wò o, emi o mu wọn lati ilẹ ariwa wá, emi o si kó wọn jọ lati àgbegbe ilẹ aiye, afọju ati ayarọ pẹlu wọn, aboyun ati ẹniti nrọbi ṣọkan pọ̀: li ẹgbẹ nlanla ni nwọn o pada sibẹ.

9. Nwọn o wá pẹlu ẹkun, pẹlu adura li emi o si ṣe amọ̀na wọn: emi o mu wọn rìn lẹba odò omi li ọ̀na ganran, nwọn kì yio kọsẹ ninu rẹ̀: nitori emi jẹ baba fun Israeli, Efraimu si li akọbi mi.

10. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin orilẹ-ède, ẹ sọ ọ ninu erekuṣu òkere, ki ẹ si wipe, Ẹniti o tú Israeli ka yio kó o jọ, yio si pa a mọ, gẹgẹ bi oluṣọ-agutan agbo-ẹran rẹ̀.

11. Nitori Oluwa ti tú Jakobu silẹ, o si rà a pada li ọwọ awọn ti o li agbara jù u lọ.

12. Njẹ, nwọn o wá, nwọn o si kọrin ni ibi giga Sioni, nwọn o si jumọ lọ sibi ore Oluwa, ani fun alikama, ati fun ọti-waini, ati fun ororo, ati fun ẹgbọrọ agbo-ẹran, ati ọwọ́-ẹran: ọkàn wọn yio si dabi ọgbà ti a bomi rin; nwọn kì yio si kãnu mọ rara.

13. Nigbana ni wundia yio yọ̀ ninu ijó, pẹlu ọdọmọkunrin ati arugbo ṣọkan pọ̀: nitori emi o sọ ọ̀fọ wọn di ayọ̀, emi o si tù wọn ninu, emi o si mu wọn yọ̀ lẹhin ikãnu wọn.

14. Emi o si fi sisanra tẹ ọkàn awọn alufa lọrun, ore mi yio si tẹ awọn enia mi lọrun, li Oluwa wi.

15. Bayi li Oluwa wi, Ni Rama li a gbọ́ ohùnrere, ẹkún kikoro; Rakeli nsọkun fun awọn ọmọ rẹ̀, kò gbipẹ nitori awọn ọmọ rẹ̀, nitoripe nwọn kò si.

16. Bayi li Oluwa wi; Dá ohùn rẹ duro ninu ẹkun, ati oju rẹ ninu omije: nitori iṣẹ rẹ ni ère, li Oluwa wi, nwọn o si pada wá lati ilẹ ọta.

17. Ireti si wà ni igbẹhin rẹ, li Oluwa wi, pe awọn ọmọ rẹ yio pada si agbegbe wọn.

18. Lõtọ emi ti gbọ́ Efraimu npohùnrere ara rẹ̀ bayi pe; Iwọ ti nà mi, emi si di ninà, bi ọmọ-malu ti a kò kọ́; yi mi pada, emi o si yipada; nitori iwọ li Oluwa Ọlọrun mi.

19. Lõtọ lẹhin ti emi yipada, mo ronupiwada; ati lẹhin ti a kọ́ mi, mo lu ẹ̀gbẹ mi: oju tì mi, lõtọ, ani mo dãmu, nitoripe emi ru ẹ̀gan igba ewe mi.

20. Ọmọ ọ̀wọn ha ni Efraimu fun mi bi? ọmọ inu-didùn ha ni? nitori bi emi ti sọ̀rọ si i to, sibẹ emi ranti rẹ̀, nitorina ni ọkàn mi ṣe lù fun u; emi o ṣe iyọ́nu fun u nitõtọ, li Oluwa wi.

21. Gbe àmi-ọ̀na soke, ṣe ọwọ̀n àmi: gbe ọkàn rẹ si opopo ọ̀na, ani ọ̀na ti iwọ ti lọ: tun yipada, iwọ wundia Israeli, tun yipada si ilu rẹ wọnyi.

22. Iwọ o ti ṣina kiri pẹ to, iwọ apẹhinda ọmọbinrin? nitori Oluwa dá ohun titun ni ilẹ na pe, Obinrin kan yio yi ọkunrin kan ka.

23. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Nwọn o si tun lò ède yi ni ilẹ Juda ati ni ilu rẹ̀ wọnni, nigbati emi o mu igbekun wọn pada, pe, Ki Oluwa ki o bukun ọ, Ibugbe ododo, Oke ìwa-mimọ́!

Ka pipe ipin Jer 31