Nigbana ni wundia yio yọ̀ ninu ijó, pẹlu ọdọmọkunrin ati arugbo ṣọkan pọ̀: nitori emi o sọ ọ̀fọ wọn di ayọ̀, emi o si tù wọn ninu, emi o si mu wọn yọ̀ lẹhin ikãnu wọn.