Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 31:15-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Bayi li Oluwa wi, Ni Rama li a gbọ́ ohùnrere, ẹkún kikoro; Rakeli nsọkun fun awọn ọmọ rẹ̀, kò gbipẹ nitori awọn ọmọ rẹ̀, nitoripe nwọn kò si.

16. Bayi li Oluwa wi; Dá ohùn rẹ duro ninu ẹkun, ati oju rẹ ninu omije: nitori iṣẹ rẹ ni ère, li Oluwa wi, nwọn o si pada wá lati ilẹ ọta.

17. Ireti si wà ni igbẹhin rẹ, li Oluwa wi, pe awọn ọmọ rẹ yio pada si agbegbe wọn.

18. Lõtọ emi ti gbọ́ Efraimu npohùnrere ara rẹ̀ bayi pe; Iwọ ti nà mi, emi si di ninà, bi ọmọ-malu ti a kò kọ́; yi mi pada, emi o si yipada; nitori iwọ li Oluwa Ọlọrun mi.

19. Lõtọ lẹhin ti emi yipada, mo ronupiwada; ati lẹhin ti a kọ́ mi, mo lu ẹ̀gbẹ mi: oju tì mi, lõtọ, ani mo dãmu, nitoripe emi ru ẹ̀gan igba ewe mi.

20. Ọmọ ọ̀wọn ha ni Efraimu fun mi bi? ọmọ inu-didùn ha ni? nitori bi emi ti sọ̀rọ si i to, sibẹ emi ranti rẹ̀, nitorina ni ọkàn mi ṣe lù fun u; emi o ṣe iyọ́nu fun u nitõtọ, li Oluwa wi.

21. Gbe àmi-ọ̀na soke, ṣe ọwọ̀n àmi: gbe ọkàn rẹ si opopo ọ̀na, ani ọ̀na ti iwọ ti lọ: tun yipada, iwọ wundia Israeli, tun yipada si ilu rẹ wọnyi.

22. Iwọ o ti ṣina kiri pẹ to, iwọ apẹhinda ọmọbinrin? nitori Oluwa dá ohun titun ni ilẹ na pe, Obinrin kan yio yi ọkunrin kan ka.

23. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Nwọn o si tun lò ède yi ni ilẹ Juda ati ni ilu rẹ̀ wọnni, nigbati emi o mu igbekun wọn pada, pe, Ki Oluwa ki o bukun ọ, Ibugbe ododo, Oke ìwa-mimọ́!

24. Juda ati gbogbo ilu rẹ̀ yio ma jumọ gbe inu rẹ̀, agbẹ, ati awọn ti mba agbo-ẹran lọ kakiri,

25. Nitori emi tù ọkàn alãrẹ ninu, emi si ti tẹ gbogbo ọkàn ikãnu lọrun.

26. Lori eyi ni mo ji, mo si wò; õrun mi si dùn mọ mi.

27. Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbin ile Israeli ati Judah ni irugbin enia, ati irugbin ẹran.

28. Yio si ṣe, pe gẹgẹ bi emi ti ṣọ́ wọn, lati fà tu, ati lati fa lulẹ, ati lati wo lulẹ, ati lati parun, ati lati pọnloju, bẹ̃ni emi o ṣọ́ wọn, lati kọ́, ati lati gbìn, li Oluwa wi.

29. Li ọjọ wọnni, nwọn kì yio wi mọ pe, Awọn baba ti jẹ eso ajara aipọn, ehín si ti kan awọn ọmọ.

30. Ṣugbọn olukuluku ni yio kú nitori aiṣedede rẹ̀, olukuluku ti o jẹ eso ajara-aipọn ni ehín yio kan.

31. Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o ba ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun.

32. Kì iṣe bi majẹmu na ti emi ba baba wọn dá li ọjọ na ti emi fà wọn lọwọ lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti: awọn ti nwọn dà majẹmu mi, bi emi tilẹ jẹ alakoso wọn sibẹ, li Oluwa wi;

Ka pipe ipin Jer 31