Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 29:20-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Njẹ ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, gbogbo ẹnyin igbekun ti emi ti ran jade lati Jerusalemu si Babeli.

21. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi, niti Ahabu ọmọ Kolaiah, ati niti Sedekiah ọmọ Maaseiah, ti nsọtẹlẹ eke fun nyin li orukọ mi; wò o, emi fi wọn le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli; on o si pa wọn li oju nyin;

22. Ati lati ọdọ wọn li a o da ọ̀rọ-egún kan silẹ li ẹnu gbogbo igbekun Juda ti o wà ni Babeli, wipe; Ki Oluwa ki o ṣe ọ bi Sedekiah, ati bi Ahabu, awọn ẹniti ọba Babeli sun ninu iná.

23. Nitori nwọn ti hùwa wère ni Israeli, nwọn si ba aya aladugbo wọn ṣe panṣaga, nwọn si ti sọ̀rọ eke li orukọ mi, ti emi kò ti pa li aṣẹ fun wọn: emi tilẹ mọ̀, emi si li ẹlẹri, li Oluwa wi.

24. Ati fun Ṣemaiah ara Nehalami, ni iwọ o sọ wipe.

25. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Nitoripe iwọ ti rán iwe li orukọ rẹ si gbogbo enia ti o wà ni Jerusalemu ati si Sefaniah, ọmọ Maaseiah, alufa, ati si gbogbo awọn alufa, wipe,

26. Oluwa ti fi ọ jẹ oyè alufa ni ipo Jehoiada, alufa, ki ẹnyin ki o lè jẹ olutọju ni ile Oluwa, nitori olukuluku aṣiwere enia, ati ẹnikẹni ti o sọ asọtẹlẹ ki iwọ ki o le fi wọn sinu tubu ati sinu àba.

27. Njẹ nisisiyi, ẽṣe ti iwọ kò ba Jeremiah ti Anatoti wi, ẹniti o nsọ asọtẹlẹ fun nyin!

28. Nitorina li o ṣe ranṣẹ si wa ni Babeli, wipe, Akoko yio pẹ: ẹ kọ́ ile, ki ẹ si ma gbe inu wọn, ẹ si gbìn ọgbà, ki ẹ ma jẹ eso wọn.

29. Sefaniah, alufa, si ka iwe yi li eti Jeremiah woli.

Ka pipe ipin Jer 29