Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 20:7-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Oluwa, iwọ ti fi ọ̀rọ rọ̀ mi, emi si gba rirọ̀! iwọ li agbara jù mi lọ, o si bori mi; emi di ẹni iyọ-ṣuti-si lojojumọ, gbogbo wọn ni ngàn mi!

8. Nitori lati igba ti mo ti sọ̀rọ, emi kigbe, mo ke, Iwa-agbara, ati iparun, nitori a sọ ọ̀rọ Oluwa di ohun ẹ̀gan ati itiju fun mi lojojumọ.

9. Nitorina mo si wipe, emi kì yio mu ni ranti rẹ̀, emi kì yio si sọ ọ̀rọ li orukọ rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn ọ̀rọ rẹ̀ mbẹ bi iná ti njó ninu mi ti a se mọ inu egungun mi, o si rẹ̀ mi lati pa a mọra, emi kò le ṣe e.

10. Nitoriti mo gbọ́ ẹgan ọ̀pọlọpọ, idãmu niha gbogbo, nwọn wipe: fi sùn, awa o si fi sùn. Gbogbo awọn ọrẹ mi, ati gbogbo awọn ẹgbẹ mi wipe: bọya a o tãn jẹ, awa o si ṣẹgun rẹ̀, a o si gbẹsan wa lara rẹ̀.

11. Ṣugbọn Oluwa mbẹ lọdọ mi bi akọni ẹlẹrù, nitorina awọn ti nṣe inunibini si mi yio ṣubu, nwọn kì yio le bori: oju yio tì wọn gidigidi, nitoripe nwọn kì o ṣe rere: a ki yio gbagbe itiju wọn lailai!

12. Oluwa awọn ọmọ-ogun, iwọ ti ndán olododo wò, iwọ si ri inu ati ọkàn, emi o ri ẹsan rẹ lara wọn: nitoriti mo ti fi ọ̀ran mi le ọ lọwọ!

13. Ẹ kọrin si Oluwa, ẹ yìn Oluwa, nitoriti o ti gbà ọkàn talaka kuro lọwọ awọn oluṣe buburu.

14. Egbe ni fun ọjọ na ti a bi mi! ọjọ na ti iya mi bi mi, ki o má ri ibukun!

15. Egbe ni fun ọkunrin na ti o mu ihìn tọ̀ baba mi wá, wipe, Ọmọkunrin li a bi fun ọ; o mu u yọ̀.

16. Ki ọkunrin na ki o si dabi ilu wọnni ti Oluwa ti bì ṣubu, li aiyi ọkàn pada, ki o si gbọ́ ẹkun li owurọ, ati ọ̀fọ li ọsangangan.

17. Nitoriti kò pa mi ni inu iya mi, tobẹ̃ ki iya mi di isà mi, ki o loyun mi lailai.

18. Ẽṣe ti emi fi jade kuro ninu iya mi, lati ri irora ati oṣi, ati lati pari ọjọ mi ni itiju?

Ka pipe ipin Jer 20