Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 10:10-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ṣugbọn Oluwa, Ọlọrun otitọ ni, on ni Ọlọrun alãye, ati Ọba aiyeraiye! aiye yio warìri nigbati o ba binu, orilẹ-ède kì yio le duro ni ibinu rẹ̀.

11. Bayi li ẹnyin o wi fun wọn pe: Awọn ọlọrun ti kò da ọrun on aiye, awọn na ni yio ṣegbe loju aiye, ati labẹ ọrun wọnyi.

12. On ti da aiye nipa agbara rẹ̀, on ti pinnu araiye nipa ọgbọ́n rẹ̀, o si nà awọn ọrun nipa oye rẹ̀.

13. Nigbati o ba sán ãrá, ọ̀pọlọpọ omi ni mbẹ loju-ọrun, o si jẹ ki kũku rú soke lati opin aiye; o da mànamana fun òjo, o si mu ẹfũfu jade lati inu iṣura rẹ̀ wá.

14. Aṣiwere ni gbogbo enia nitori oye kò si: oju tì olukuluku alagbẹdẹ niwaju ere rẹ̀, nitori ère didà rẹ̀ eke ni, kò si sí ẹmi ninu rẹ̀.

15. Asan ni nwọn, ati iṣẹ iṣina: nigba ibẹwo wọn nwọn o ṣègbe.

16. Ipin Jakobu kò si dabi wọn nitori on ni iṣe Ẹlẹda ohun gbogbo; Israeli si ni ẹya ijogun rẹ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.

17. Ko ẹrù rẹ kuro ni ilẹ na, Iwọ olugbe ilu ti a dotì.

18. Nitori bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o gbọ̀n awọn olugbe ilẹ na nù lẹ̃kan yi, emi o si pọ́n wọn loju, ki nwọn ki o le ri i.

19. Egbe ni fun mi nitori ipalara mi! ọgbẹ mi pọ̀: ṣugbọn mo wipe, nitõtọ ìya mi ni eyi, emi o si rù u.

20. Agọ mi bajẹ, gbogbo okùn mi si ja: awọn ọmọ mi ti fi mi silẹ lọ, nwọn kò sí mọ́, kò si ẹnikan ti yio nà agọ mi mọ, ti yio si ta aṣọ ikele mi.

21. Nitori awọn oluṣọ agutan ti di ope, nwọn kò si wá Oluwa: nitorina nwọn kì yio ri rere, gbogbo agbo wọn yio si tuka.

22. Sa wò o, ariwo igbe ti de, ati irukerudo nla lati ilẹ ariwa wá, lati sọ ilu Judah di ahoro, ati iho ọwawa.

23. Oluwa! emi mọ̀ pe, ọ̀na enia kò si ni ipa ara rẹ̀: kò si ni ipá enia ti nrin, lati tọ́ iṣisẹ rẹ̀.

24. Oluwa kilọ fun mi, ṣugbon ni idajọ ni, ki o máṣe ni ibinu rẹ, ki iwọ ki o má sọ mi di asan.

Ka pipe ipin Jer 10