Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 5:11-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Egbe ni fun awọn ti ima dide ni kùtukutu, ki nwọn le ma lepa ọti lile; ti nwọn wà ninu rẹ̀ titi di alẹ, titi ọti-waini mu ara wọn gbona!

12. Ati durù, ati fioli, tabreti, ferè, ati ọti-waini wà ninu àse wọn: ṣugbọn nwọn kò kà iṣẹ Oluwa si, bẹ̃ni nwọn kò rò iṣẹ ọwọ́ rẹ̀.

13. Nitorina awọn enia mi lọ si oko-ẹrú, nitoriti oye kò si, awọn ọlọla wọn di rirù, ati ọ̀pọlọpọ wọn gbẹ fun orùngbẹ.

14. Nitorina ipò-òkú ti fun ara rẹ̀ li àye, o si là ẹnu rẹ̀ li aini ìwọn: ati ogo wọn, ati ọ̀pọlọpọ wọn, ati ọṣọ́ wọn, ati awọn ẹniti nyọ̀, yio sọkalẹ sinu rẹ̀.

15. Enia lasan li a o rẹ̀ silẹ, ati ẹni-alagbara li a o rẹ̀ silẹ, oju agberaga li a o si rẹ̀ silẹ.

16. Ṣugbọn Oluwa awọn ọmọ-ogun li a o gbe ga ni idajọ, ati Ọlọrun Ẹni-Mimọ́ yio jẹ mimọ́ ninu ododo.

17. Nigbana li awọn ọdọ-agutan yio ma jẹ̀ gẹgẹ bi iṣe wọn, ati ibi ahoro awọn ti o sanra li awọn alejò yio ma jẹ.

18. Egbe ni fun awọn ti nfi ohun asan fà ìwa buburu, ati awọn ti o dabi ẹnipe nfi okùn kẹkẹ́ fà ẹ̀ṣẹ.

19. Awọn ti o wipe, Jẹ ki o yara, ki o si mu iṣẹ rẹ̀ yara, ki awa ki o le ri i: ati jẹ ki ìmọ Ẹni-Mimọ́ Israeli sunmọ ihin, ki o si wá, ki awa ki o le mọ̀ ọ.

20. Egbe ni fun awọn ti npè ibi ni rere, ati rere ni ibi, ti nfi okùnkun ṣe imọlẹ, ati imọlẹ ṣe okùnkun: ti nfi ikorò pe adùn, ati adùn pe ikorò!

21. Egbe ni fun awọn ti nwọn gbọ́n li oju ara wọn, ti nwọn si mọ̀ oye li oju ara wọn!

22. Egbe ni fun awọn ti o ni ipá lati mu ọti-waini, ati awọn ọkunrin alagbara lati ṣe adàlu ọti lile:

23. Awọn ẹniti o da are fun ẹni-buburu nitori ère, ti nwọn si mu ododo olododo kuro li ọwọ́ rẹ̀.

24. Nitorina bi iná ti ijo akekù koriko run, ti ọwọ́ iná si ijo iyàngbo; bẹ̃ni egbò wọn yio da bi rirà; itanna wọn yio si gòke bi ekuru; nitori nwọn ti ṣá ofin Oluwa awọn ọmọ-ogun tì, nwọn si ti gàn ọ̀rọ Ẹni-Mimọ Israeli.

25. Nitorina ni ibinu Oluwa fi ràn si enia rẹ̀, o si ti na ọwọ́ rẹ̀ si wọn, o si ti lù wọn: awọn òke si warìri, okú wọn si wà bi igbẹ li ãrin igboro. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.

26. Yio si gbe ọpágun soke si awọn orilẹ-ède ti o jìna, yio si kọ si wọn lati opin ilẹ wá, si kiyesi i, nwọn o yara wá kánkán.

27. Kò si ẹniti yio rẹ̀, tabi ti yio kọsẹ ninu wọn, kò si ẹniti yio tõgbe tabi ti yio sùn: bẹ̃ni amùre ẹgbẹ wọn kì yio tu, bẹ̃ni okùn bàta wọn kì yio ja.

28. Awọn ẹniti ọfà wọn mu, ti gbogbo ọrun wọn si kàn, a o ka patakò ẹsẹ ẹṣin wọn si okuta akọ, ati kẹkẹ́ wọn bi ãja.

29. Kike wọn yio dabi ti kiniun, nwọn o ma ke bi awọn ọmọ kiniun, nitõtọ nwọn o ma ke, nwọn o si di ohun ọdẹ na mu, nwọn a si gbe e lọ li ailewu, kò si ẹnikan ti yio gbà a.

Ka pipe ipin Isa 5