Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 49:15-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Obinrin ha lè gbagbe ọmọ ọmú rẹ̀ bi, ti kì yio fi ṣe iyọ́nu si ọmọ inu rẹ̀? lõtọ, nwọn le gbagbe, ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ.

16. Kiye si i, emi ti kọ ọ si atẹlẹwọ mi: awọn odi rẹ mbẹ niwaju mi nigbagbogbo.

17. Awọn ọmọ rẹ yára; awọn oluparun rẹ ati awọn ti o fi ọ ṣofò yio ti ọdọ rẹ jade.

18. Gbe oju rẹ soke yika kiri, si kiyesi i: gbogbo awọn wọnyi ṣà ara wọn jọ, nwọn si wá sọdọ rẹ. Oluwa wipe, Bi mo ti wà, iwọ o fi gbogbo wọn bò ara rẹ, bi ohun ọṣọ́, nitõtọ, iwọ o si há wọn mọ ara, bi iyawo.

19. Nitori ibi ofò rẹ, ati ibi ahoro rẹ wọnni, ati ilẹ iparun rẹ, yio tilẹ há jù nisisiyi, nitori awọn ti ngbe inu wọn, awọn ti o gbe ọ mì yio si jinà rére.

20. Awọn ọmọ-ọmọ rẹ ti o ti nù yio tun wi li eti rẹ pe, Ayè kò gbà mi, fi ayè fun mi lati ma gbé.

21. Nigbana ni iwọ o wi li ọkàn rẹ pe, Tali o bi awọn wọnyi fun mi, mo sa ti wà li ailọmọ ati li àgan, igbèkun ati ẹni-iṣikiri? tani o si ti tọ́ awọn wọnyi dagba? Kiyesi i, a fi emi nikan silẹ, awọn wọnyi, nibo ni nwọn gbe ti wà.

22. Bayi ni Oluwa Jehofa wi, Kiyesi i, emi o gbe ọwọ́ mi soke si awọn Keferi, emi o si gbe ọpágun mi soke si awọn enia, nwọn o si gbe awọn ọmọkunrin rẹ wá li apa wọn, a o si gbe awọn ọmọbinrin rẹ li ejìka wọn.

23. Awọn ọba yio jẹ baba olutọju rẹ, awọn ayaba wọn yio si jẹ iya olutọju rẹ; ni idojubolẹ ni nwọn o ma tẹriba fun ọ, nwọn o si lá ekuru ẹsẹ rẹ; iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa; nitori oju kì yio tì awọn ti o ba duro dè mi.

24. A ha le gba ikogun lọwọ alagbara bi? tabi a le gbà awọn ondè lọwọ awọn ẹniti nwọn tọ́ fun?

25. Ṣugbọn bayi ni Oluwa wi, a o tilẹ̀ gbà awọn ondè kuro lọwọ awọn alagbara, a o si gbà ikogun lọwọ awọn ẹni-ẹ̀ru; nitori ẹniti o mba ọ jà li emi o ba jà, emi o si gbà awọn ọmọ rẹ là.

Ka pipe ipin Isa 49