Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 47:5-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Joko, dakẹ jẹ, lọ sinu okùnkun, iwọ ọmọbinrin ara Kaldea, nitori a ki yio pe ọ ni Iyálode awọn ijọba mọ.

6. Emi ti binu si enia mi, emi ti sọ ilẹ ini mi di aimọ́, mo si ti fi wọn le ọ lọwọ: iwọ kò kãnu wọn, iwọ fi ajàga wuwo le awọn alagba lori.

7. Iwọ si wipe, Emi o ma jẹ Iyalode titi lai: bẹ̃ni iwọ kò fi nkan wọnyi si aiya rẹ, bẹ̃ni iwọ kò ranti igbẹhin rẹ.

8. Nitorina gbọ́ eyi, iwọ alafẹ́, ti o joko li ainani, ti o wi li ọkàn rẹ pe, Emi ni, kò si si ẹlomiran lẹhin mi: emi ki yio joko bi opo, bẹ̃ni emi ki yio mọ̀ òfo ọmọ.

9. Ṣugbọn nkan meji wọnyi ni yio deba ọ li ojiji, li ọjọ kan, òfo ọmọ ati opo: nwọn o ba ọ perepere, nitori ọpọlọpọ iṣẹ́ ajẹ́ rẹ, ati nitori ọpọlọpọ iṣẹ́ afọṣẹ rẹ.

10. Nitori ti iwọ ti gbẹkẹle ìwa buburu rẹ: iwọ ti wipe, Kò si ẹnikan ti o ri mi. Ọgbọ́n rẹ ati ìmọ rẹ, o ti mu ọ ṣinà; iwọ si ti wi li ọkàn rẹ pe, Emi ni, ko si ẹlomiran lẹhin mi.

Ka pipe ipin Isa 47