Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 44:16-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Apakan ninu rẹ̀ li o fi dá iná, apakan ninu rẹ̀ li o fi jẹ ẹran: o sun sisun, o si yo, o yá iná pẹlu, o si wipe, Ahã, ara mi gbona, mo ti ri iná.

17. Iyokù rẹ̀ li o si fi ṣe ọlọrun, ani ere gbigbẹ́ rẹ̀, o foribalẹ fun u, o sìn i, o gbadura si i, o si wipe, Gbà mi; nitori iwọ li ọlọrun mi.

18. Nwọn kò mọ̀, oye ko si ye wọn: nitori o dí wọn li oju, ki nwọn ki o má le ri; ati aiya wọn, ki oye ki o má le ye wọn.

19. Kò si ẹniti o rò li ọkàn rẹ̀, bẹ̃ni ko si imọ̀ tabi oye lati wipe, Mo ti fi apakan rẹ̀ da iná; mo si din akara pẹlu lori ẹyin iná rẹ̀: mo ti sun ẹran, mo si jẹ ẹ: emi o ha fi iyokù rẹ̀ ṣe irira? emi o ha foribalẹ fun ìti igi?

20. O fi ẽru bọ́ ara rẹ̀: aiya ẹtàn ti dari rẹ̀ si apakan, ti kò le gbà ọkàn rẹ̀ là, bẹ̃ni kò le wipe, Eke ko ha wà li ọwọ́ ọtun mi?

21. Ranti wọnyi, Jakobu ati Israeli; nitori iwọ ni iranṣẹ mi: Emi ti mọ ọ; iranṣẹ mi ni iwọ, Israeli; iwọ ki yio di ẹni-igbagbe lọdọ mi.

22. Mo ti pa irekọja rẹ rẹ́, bi awọsanma ṣiṣú dùdu, ati ẹ̀ṣẹ rẹ, bi kũku: yipada sọdọ mi; nitori mo ti rà ọ pada.

23. Kọrin, ẹnyin ọrun; nitori Oluwa ti ṣe e: kigbe, ẹnyin isalẹ aiye; bú si orin, ẹnyin oke-nla, igbó, ati gbogbo igi inu rẹ̀; nitori Oluwa ti rà Jakobu pada, o si ṣe ara rẹ̀ logo ni Israeli.

24. Bayi ni Oluwa, Olurapada rẹ wi, ati ẹniti o mọ ọ lati inu wá: emi li Oluwa ti o ṣe ohun gbogbo; ti o nikan nà awọn ọrun; ti mo si tikara mi tẹ́ aiye.

Ka pipe ipin Isa 44