Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 42:12-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Jẹ ki wọn fi ogo fun Oluwa, ki wọn si wi iyìn rẹ̀ ninu erekùṣu.

13. Oluwa yio jade bi ọkunrin alagbara, yio rú owú soke bi ologun: yio kigbé, nitõtọ, yio ké ramuramu; yio bori awọn ọta rẹ̀.

14. Lailai ni mo ti dakẹ́: mo ti gbe jẹ, mo ti pa ara mi mọra; nisisiyi emi o ké bi obinrin ti nrọbi; emi o parun, emi o si gbé mì lẹ̃kanna.

15. Emi o sọ oke-nla ati òke-kékèké di ofo, emi o si mú gbogbo ewebẹ̀ wọn gbẹ: emi o sọ odò ṣiṣàn di iyangbẹ́ ilẹ, emi o si mú abàta gbẹ.

16. Emi o si mu awọn afọju bá ọ̀na ti nwọn kò mọ̀ wá; emi o tọ́ wọn ninu ipa ti wọn kò ti mọ̀; emi o sọ okùnkun di imọlẹ niwaju wọn, ati ohun wiwọ́ di titọ. Nkan wọnyi li emi o ṣe fun wọn, emi kì yio si kọ̀ wọn silẹ.

17. A o dá awọn ti o gbẹkẹle ere gbigbẹ́ padà, a o doju tì wọn gidigidi, awọn ti nwi fun ere didà pe, Ẹnyin ni ọlọrun wa.

18. Gbọ́, ẹnyin aditi; ki ẹ si wò, ẹnyin afọju ki ẹnyin ki o le ri i.

19. Tani afọju, bikoṣe iranṣẹ mi? tabi aditi, bi ikọ̀ mi ti mo rán? tani afọju bi ẹni pipé? ti o si fọju bi iranṣẹ Oluwa?

20. Ni riri nkan pupọ, ṣugbọn iwọ kò kiyesi i; ni ṣiṣi eti, ṣugbọn on ko gbọ́.

21. Inu Oluwa dùn gidigidi nitori ododo rẹ̀; yio gbe ofin ga, yio si sọ ọ di ọlọlá.

22. Ṣugbọn enia ti a jà lole ti a si ko li ẹrù ni eyi: gbogbo wọn li a dẹkùn mu ninu ihò, a fi wọn pamọ ninu tubu: a fi wọn fun ikogun, ẹnikan ko si gbà wọn; a fi wọn fun ikogun, ẹnikan ko si wipe, Mu u pada.

23. Tani ninu nyin ti o fi eti si eyi? ti o dẹti silẹ, ti yio si gbọ́ eyi ti mbọ̀ lẹhin?

24. Tani fi Jakobu fun ikogun, ti o si fi Israeli fun ole? Oluwa ha kọ́ ẹniti a ti dẹṣẹ si? nitori nwọn kò fẹ rìn li ọ̀na rẹ̀, bẹ̃ni nwọn ko gbọ́ ti ofin rẹ̀.

25. Nitorina ni o ṣe dà irúnu ibinu rẹ̀ si i lori, ati agbara ogun: o si ti tẹ̀ iná bọ̀ ọ yika, ṣugbọn on kò mọ̀; o si jo o, ṣugbọn on kò kà a si.

Ka pipe ipin Isa 42