Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 30:26-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Imọ́lẹ oṣupa yio si dabi imọ́lẹ õrun, imọ́lẹ õrun yio si ràn ni iwọ̀n igbà meje, bi imọ́lẹ ọjọ meje, li ọjọ ti Oluwa dí yiya awọn enia rẹ̀, ti o si ṣe àwotán ọgbẹ ti a ṣá wọn.

27. Kiyesi i, orukọ Ọluwa mbọ̀ lati ọ̀na jijin wá, ibinu rẹ̀ si njo, ẹrù rẹ̀ si wuwo: ète rẹ̀ si kún fun ikannu, ati ahọn rẹ̀ bi ajonirun iná:

28. Ẽmi rẹ̀ bi kikun omi, yio si de ãrin-meji ọrùn, lati fi kọ̀nkọsọ kù awọn orilẹ-ède: ijanu yio si wà li ẹ̀rẹkẹ́ awọn enia, lati mu wọn ṣina.

29. Ẹnyin o li orin kan, gẹgẹ bi igbati a nṣe ajọ li oru; ati didùn inu, bi igbati ẹnikan fun fère lọ, lati wá si òke-nla Oluwa, sọdọ Apata Israeli.

30. Oluwa yio si mu ki a gbọ́ ohùn ogo rẹ̀, yio si fi isọkalẹ apá rẹ̀ hàn pẹlu ikannu ibinu rẹ̀, ati pẹlu ọwọ́ ajonirun iná, pẹlu ifúnka, ati ijì, ati yinyín.

31. Nitori nipa ohùn Oluwa li a o fi lù awọn ara Assiria bo ilẹ, ti o fi kùmọ lù.

32. Ati nibi gbogbo ti paṣán ti a yàn ba kọja si, ti Oluwa yio fi lé e, yio ṣe pẹlu tabreti ati dùru: yio si fi irọ́kẹ̀kẹ ogun bá a jà.

33. Nitori a ti yàn Tofeti lati igbà atijọ; nitõtọ, ọba li a ti pèse rẹ̀ fun; o ti ṣe e ki o jìn, ki o si gbòro: okiti rẹ̀ ni iná ati igi pupọ; emi Oluwa, bi iṣàn imí-ọjọ́ ntàn iná ràn a.

Ka pipe ipin Isa 30