Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 9:18-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Àtẹgun mẹfa ni itẹ́ na ni, pẹlu apoti-itisẹ wura kan, ti a dè mọ itẹ́ na, ati irọpa ni iha mejeji ibi ijoko na, kiniun meji si duro lẹba awọn irọpa na.

19. Kiniun mejila si duro lori atẹgun mẹfẹfa na, ni iha ekini ati ni iha ekeji. A kò ṣe iru rẹ̀ ri ni gbogbo ijọba.

20. Ati gbogbo ohun-elo mimu Solomoni ọba jẹ wura, ati gbogbo ohun-elo ile igbo Lebanoni, wura daradara ni: kò si ti fadakà; a kò kà fadakà si nkankan li ọjọ Solomoni.

21. Nitori awọn ọkọ̀ ọba nlọ si Tarṣiṣi pẹlu awọn iranṣẹ Huramu; ẹ̃kan li ọdun mẹta li awọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ide, nwọn nmu wura, ati fadakà, ati ehin-erin, ati inaki, ati ẹiyẹ-ologe wá.

22. Solomoni ọba si tobi jù gbogbo ọba aiye lọ li ọrọ̀ ati li ọgbọn.

23. Gbogbo awọn ọba aiye si nwá oju Solomoni, lati gbọ́ ọgbọ́n rẹ̀ ti Ọlọrun ti fi si i li ọkàn.

24. Olukuluku si mu ọrẹ tirẹ̀ wá, ohun-elo fadakà ati ohun-elo wura, ati aṣọ ibora, ihamọra, ati turari, ẹṣin, ati ibaka, iye kan li ọdọdun.

25. Solomoni si ni ẹgbaji ile fun ẹṣin ati kẹkẹ́, ati ẹgbafa ẹlẹṣin, ti o fi si awọn ilu kẹkẹ́, ati ọdọ ọba ni Jerusalemu.

26. O si jọba lori gbogbo awọn ọba lati odò (Euferate) titi de ilẹ awọn ara Filistia ati de àgbegbe Egipti.

27. Ọba si sọ fadakà dabi okuta ni Jerusalemu, ati igi-kedari li o si ṣe bi sikamore, ti o wà ni pẹtẹlẹ li ọ̀pọlọpọ.

28. Nwon si mu ẹṣin tọ̀ Solomoni lati Egipti wá, ati lati ilẹ gbogbo.

29. Ati iyokù iṣe Solomoni ti iṣaju ati ti ikẹhin, a kọ ha kọ wọn sinu iwe Natani woli, ati sinu asọtẹlẹ Ahijah, ara Ṣilo, ati sinu iran Iddo, ariran, sipa Jeroboamu, ọmọ Nebati.

30. Solomoni si jọba ni Jerusalemu lori gbogbo Israeli li ogoji ọdun.

31. Solomoni si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i ni ilu Dafidi baba rẹ̀: Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 2. Kro 9