Nitori awọn ọkọ̀ ọba nlọ si Tarṣiṣi pẹlu awọn iranṣẹ Huramu; ẹ̃kan li ọdun mẹta li awọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ide, nwọn nmu wura, ati fadakà, ati ehin-erin, ati inaki, ati ẹiyẹ-ologe wá.