Àtẹgun mẹfa ni itẹ́ na ni, pẹlu apoti-itisẹ wura kan, ti a dè mọ itẹ́ na, ati irọpa ni iha mejeji ibi ijoko na, kiniun meji si duro lẹba awọn irọpa na.