Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 34:8-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Njẹ li ọdun kejidilogun ijọba rẹ̀, nigbati o ti wẹ̀ ilẹ na mọ́, ati ile na, o rán Ṣafani, ọmọ Asaliah, ati Maaseiah, olori ilu na, ati Joa, ọmọ Joahasi, akọwe iranti, lati tun ile Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ṣe.

9. Nigbati nwọn si de ọdọ Hilkiah, olori alufa, nwọn fi owo na ti a mu wá sinu ile Ọlọrun le e lọwọ, ti awọn ọmọ Lefi, ti o ntọju ilẹkun, ti kójọ lati ọwọ Manasse ati Efraimu, ati lati ọdọ gbogbo awọn iyokù Israeli, ati lati gbogbo Juda ati Benjamini: nwọn si pada si Jerusalemu.

10. Nwọn si fi i le ọwọ awọn ti nṣiṣẹ na, ti nṣe alabojuto iṣẹ ile Oluwa, nwọn si fi i fun awọn aṣiṣẹ ti nṣiṣẹ ile Oluwa, lati tun ile na ṣe:

11. Awọn ọlọnà ati awọn kọlekọle ni nwọn fifun lati ra okuta gbigbẹ́, ati ìti-igi fun isopọ̀, ati lati tẹ́ ile wọnni ti awọn ọba Juda ti bajẹ.

12. Awọn ọkunrin na fi otitọ ṣiṣẹ na: awọn alabojuto wọn ni Jahati ati Obadiah, awọn ọmọ Lefi, ninu awọn ọmọ Merari; ati Sekariah ati Meṣullamu, ninu awọn ọmọ Kohati, lati mu iṣẹ lọ; ati gbogbo awọn ọmọ Lefi, ti o ni ọgbọ́n ohun-elo orin.

13. Nwọn si wà lori awọn alãru, ati awọn alabojuto gbogbo awọn ti nṣiṣẹ, ninu ìsinkisin ati ninu awọn ọmọ Lefi ni akọwe, ati olutọju ati adèna.

14. Nigbati nwọn si mu owo na ti a mu wá sinu ile Oluwa jade wá, Hilkiah alufa, ri iwe ofin Oluwa ti a ti ọwọ Mose kọ.

15. Hilkiah si dahùn o si wi fun Ṣafani, akọwe, pe, Emi ri iwe ofin ninu ile Oluwa, Hilkiah si fi iwe na le Ṣafani lọwọ.

16. Ṣafani si mu iwe na tọ̀ ọba lọ, o si mu èsi pada fun ọba wá wipe, Gbogbo eyi ti a fi le awọn iranṣẹ rẹ lọwọ, nwọn ṣe e.

17. Nwọn si ti kó gbogbo owo ti a ri ni ile Oluwa jọ, nwọn si ti fi le ọwọ awọn alabojuto, ati le ọwọ awọn ti nṣiṣẹ.

18. Nigbana ni Ṣafani, akọwe, wi fun ọba pe, Hilkiah alufa, fun mi ni iwe kan. Ṣafani si kà a niwaju ọba.

19. O si ṣe, nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ ofin na, o si fa aṣọ rẹ̀ ya.

20. Ọba si paṣẹ fun Hilkiah ati Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Abdoni, ọmọ Mika, ati Ṣafani, akọwe, ati Asaiah, iranṣẹ ọba, wipe,

21. Ẹ lọ, ẹ bere lọwọ Oluwa fun mi, ati fun awọn ti o kù ni Israeli ati ni Juda, niti ọ̀rọ iwe ti a ri: nitori titobi ni ibinu Oluwa ti a tú jade sori wa, nítori awọn bàba wa kò pa ọ̀rọ Oluwa mọ́, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu iwe yi.

22. Ati Hilkiah, ati awọn ti ọba ti yàn tọ̀ Hulda, woli obinrin, lọ, aya Ṣallumu, ọmọ Tikehati, ọmọ Hasra, olutọju aṣọ (njẹ, o ngbe Jerusalemu, niha keji;) nwọn si ba a sọ̀rọ na.

23. O si dá wọn lohùn pe, Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli wi, Ẹ sọ fun ọkunrin na ti o rán nyin si mi pe,

24. Bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o mu ibi wá si ihinyi ati si awọn ti ngbe ibẹ na, ani gbogbo egún ti a kọ sinu iwe ti nwọn ti kà niwaju ọba Juda:

25. Nitoriti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si ti sun turari fun awọn ọlọrun miran, ki nwọn ki o le fi gbogbo iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu; nitorina li a o ṣe tú ibinu mi sori ihinyi, a kì yio si paná rẹ̀.

Ka pipe ipin 2. Kro 34