Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 34:24-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o mu ibi wá si ihinyi ati si awọn ti ngbe ibẹ na, ani gbogbo egún ti a kọ sinu iwe ti nwọn ti kà niwaju ọba Juda:

25. Nitoriti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si ti sun turari fun awọn ọlọrun miran, ki nwọn ki o le fi gbogbo iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu; nitorina li a o ṣe tú ibinu mi sori ihinyi, a kì yio si paná rẹ̀.

26. Bi o si ṣe ti ọba Juda nì, ẹniti o rán nyin lati bère lọwọ Oluwa, Bayi ni ki ẹnyin ki o wi fun u, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi niti ọ̀rọ wọnni ti iwọ ti gbọ́:

27. Nitoriti ọkàn rẹ rọ̀, ti iwọ si rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju Ọlọrun, nigbati iwọ gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ si ihinyi, ati si awọn ti ngbe ibẹ, ti iwọ si rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju mi, ti iwọ si fa aṣọ rẹ ya, ti iwọ si sọkun niwaju mi; ani emi ti gbọ́ tirẹ pẹlu, li Oluwa wi.

28. Kiyesi i, emi o kó ọ jọ sọdọ awọn baba rẹ, a o si kó ọ jọ si isa-okú rẹ li alafia, bẹ̃ni oju rẹ kì yio ri gbogbo ibi ti emi o mu wá si ihinyi, ati sori awọn ti ngbe ibẹ. Bẹ̃ni nwọn mu èsi pada fun ọba wá.

29. Nigbana ni ọba ranṣẹ, nwọn si kó gbogbo awọn àgba Juda ati Jerusalemu jọ.

30. Ọba si gòke lọ sinu ile Oluwa, ati gbogbo ọkunrin Juda, ati awọn ti ngbe Jerusalemu, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo enia ati ẹni-nla ati ẹni-kekere: o si kà gbogbo ọ̀rọ inu iwe majẹmu na ti a ri ninu ile Oluwa li eti wọn.

31. Ọba si duro ni ipò rẹ̀, o si dá majẹmu niwaju Oluwa lati ma fi gbogbo aiya ati gbogbo ọkàn rìn tọ̀ Oluwa lẹhin, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati ẹri rẹ̀, ati aṣẹ rẹ̀, lati ṣe ọ̀rọ majẹmu na ti a kọ sinu iwe yi.

32. O si mu ki gbogbo awọn ti o wà ni Jerusalemu ati Benjamini duro ninu rẹ̀, awọn ti ngbe Jerusalemu si ṣe gẹgẹ bi majẹmu Ọlọrun, Ọlọrun awọn baba wọn.

Ka pipe ipin 2. Kro 34