Ọba si gòke lọ sinu ile Oluwa, ati gbogbo ọkunrin Juda, ati awọn ti ngbe Jerusalemu, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo enia ati ẹni-nla ati ẹni-kekere: o si kà gbogbo ọ̀rọ inu iwe majẹmu na ti a ri ninu ile Oluwa li eti wọn.