Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 32:3-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. O ba awọn ijoye rẹ̀ ati awọn ọkunrin alagbara rẹ̀ gbìmọ, lati dí omi orisun wọnni, ti mbẹ lẹhin ilu: nwọn si ràn a lọwọ.

4. Bẹ̃li ọ̀pọlọpọ enia kojọ pọ̀, awọn ẹniti o dí gbogbo orisun, ati odò ti nṣàn la arin ilẹ na ja, wipe, Nitori kili awọn ọba Assiria yio ṣe wá, ki nwọn ki o si ri omi pupọ̀?

5. O mu ara rẹ̀ le pẹlu, o si mọ gbogbo odi ti o ti ya, o si gbé e ga de awọn ile-iṣọ, ati odi miran lode, o si tun Millo ṣe ni ilu Dafidi, o si ṣe ọ̀kọ ati apata li ọ̀pọlọpọ.

6. O si yàn awọn balogun lori awọn enia, o si kó wọn jọ pọ̀ sọdọ rẹ̀ ni ita ẹnu-bode ilu, o si sọ̀rọ iyanju fun wọn, wipe,

7. Ẹ mu ara le, ki ẹ si ṣe onigboya, ẹ má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki aiya ki o máṣe fò nyin nitori ọba Assiria, tabi nitori gbogbo ọ̀pọlọpọ enia ti o wà pẹlu rẹ̀; nitori awọn ti o pẹlu wa jù awọn ti o pẹlu rẹ̀ lọ:

8. Apa ẹran-ara li o pẹlu rẹ̀, ṣugbọn Oluwa Ọlọrun wa li o pẹlu wa lati ràn wa lọwọ, ati lati jà ogun wa. Awọn enia na si gbẹkẹ wọn le ọ̀rọ Hesekiah, ọba Juda.

9. Lẹhin eyi ni Sennakeribu, ọba Assiria, rán awọn iranṣẹ si Jerusalemu, (ṣugbọn on tikararẹ̀ dótì Lakiṣi ati gbogbo ogun rẹ̀ pẹlu rẹ̀) sọdọ Hesekiah, ọba Juda ati sọdọ gbogbo Juda ti o wà ni Jerusalemu wipe,

10. Bayi ni Sennakeribu, ọba Assiria, wi pe, Kili ẹnyin gbẹkẹle, ti ẹnyin joko ninu odi agbara ni Jerusalemu?

11. Kò ṣepe Hesekiah ntàn nyin lati fi ara nyin fun ikú, nipa ìyan, ati nipa ongbẹ, o nwipe, Oluwa, Ọlọrun wa, yio gbà wa lọwọ ọba Assiria?

12. Kò ṣepe Hesekiah kanna li o mu ibi giga rẹ̀ wọnni kuro, ati pẹpẹ rẹ̀, ti o si paṣẹ fun Juda ati Jerusalemu, wipe, Ki ẹnyin ki o mã sìn niwaju pẹpẹ kan, ki ẹnyin ki o mã sun turari lori rẹ̀?

13. Enyin kò ha mọ̀ ohun ti emi ati awọn baba mi ti ṣe si gbogbo enia ilẹ miran? awọn oriṣa awọn orilẹ-ède ilẹ wọnni ha le gbà ilẹ wọn lọwọ mi rara?

14. Tani ninu gbogbo awọn oriṣa orilẹ-ède wọnni, ti awọn baba mi parun tũtu, ti o le gbà enia rẹ̀ lọwọ mi, ti Ọlọrun nyin yio fi le gbà nyin lọwọ mi?

15. Njẹ nitorina, ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah ki o tàn nyin jẹ, bẹ̃ni ki o máṣe rọ̀ nyin bi iru eyi, bẹ̃ni ki ẹ máṣe gbà a gbọ́: nitoriti kò si oriṣa orilẹ-ède tabi ijọba kan ti o le gbà enia rẹ̀ lọwọ mi, ati lọwọ awọn baba mi: ambọtori Ọlọrun nyin ti yio fi gbà nyin lọwọ mi?

16. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si sọ jù bẹ̃ lọ si Oluwa Ọlọrun, ati si iranṣẹ rẹ̀, Hesekiah.

17. O kọ iwe pẹlu lati kẹgan Oluwa, Ọlọrun Israeli, ati lati sọ̀rọ òdi si i, wipe, Gẹgẹ bi awọn oriṣa orilẹ-ède ilẹ miran kò ti gbà awọn enia wọn lọwọ mi, bẹ̃li Ọlọrun Hesekiah kì yio gbà awọn enia rẹ̀ lọwọ mi.

18. Nigbana ni nwọn kigbe li ohùn rara li ède Juda si awọn enia Jerusalemu ti mbẹ lori odi, lati dẹruba wọn, ati lati dãmu wọn; ki nwọn ki o le kó ilu na.

19. Nwọn si sọ̀rọ òdi si Ọlọrun Jerusalemu, bi ẹnipe si awọn oriṣa enia ilẹ aiye, ti iṣe iṣẹ ọwọ enia.

20. Ati nitori eyi ni Hesekiah, ọba, ati Isaiah woli, ọmọ Amosi, gbadura, nwọn si kigbe si ọrun.

21. Oluwa si rán Angeli kan, ẹniti o pa gbogbo awọn alagbara ogun, ati awọn aṣãju, ati awọn balogun ni ibudo ọba Assiria. Bẹ̃li o fi itiju pada si ilẹ on tikararẹ̀. Nigbati o si wá sinu ile oriṣa rẹ̀, awọn ti o ti inu ara rẹ̀ jade si fi idà pa a nibẹ.

Ka pipe ipin 2. Kro 32