Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 32:22-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Bayi li Oluwa gbà Hesekiah ati awọn ti ngbe Jerusalemu lọwọ Sennakeribu ọba Assiria, ati lọwọ gbogbo awọn omiran, o si ṣọ́ wọn ni iha gbogbo.

23. Ọ̀pọlọpọ si mu ẹ̀bun fun Oluwa wá si Jerusalemu, ati ọrẹ fun Hesekiah, ọba Juda: a si gbé e ga loju gbogbo orilẹ-ède lẹhin na.

24. Li ọjọ wọnni, Hesekiah ṣe aisan de oju ikú, o si gbadura si Oluwa; O si da a lohùn, O si fi àmi kan fun u.

25. Ṣugbọn Hesekiah kò si tun pada san gẹgẹ bi ore ti a ṣe fun u: nitoriti ọkàn rẹ̀ gbega: nitorina ni ibinu ṣe wà lori rẹ̀, lori Juda, ati lori Jerusalemu.

26. Ṣugbọn Hesekiah rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, niti igberaga ọkàn rẹ̀, ati on ati awọn ti ngbe Jerusalemu, bẹ̃ni ibinu Oluwa kò wá sori wọn li ọjọ Hesekiah.

27. Hesekiah si li ọrọ̀ li ọ̀pọlọpọ ati ọlá: o si ṣe ibi-iṣura fun ara rẹ̀ fun fadakà, ati fun wura, ati fun okuta iyebiye, ati fun turari ati fun apata, ati fun oniruru ohun-elo iyebiye.

28. Ile-iṣura pẹlu fun ibisi ọkà, ati ọti-waini; ati ororo; ati ile fun gbogbo oniruru ẹran, ati ọgbà fun agbo-ẹran.

29. Pẹlupẹlu o ṣe ilu fun ara rẹ̀, ati agbo agutan ati agbo malu li ọ̀pọlọpọ: nitoriti Ọlọrun fun u li ọrọ̀ li ọ̀pọlọpọ.

30. Hesekiah kanna yi li o dí ipa-omi ti o wà li òke Gihoni pẹlu, o si mu u wá isalẹ tara si iha iwọ-õrun ilu Dafidi. Hesekiah si ṣe rere ni gbogbo iṣẹ rẹ̀.

31. Ṣugbọn niti awọn ikọ̀ awọn ọmọ-alade Babeli, ti nwọn ranṣẹ si i, lati bère ohun-iyanu ti a ṣe ni ilẹ na, Ọlọrun fi i silẹ lati dán a wò, ki o le mọ̀ ohun gbogbo ti o wà li ọkàn rẹ̀.

Ka pipe ipin 2. Kro 32