Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 32:11-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Kò ṣepe Hesekiah ntàn nyin lati fi ara nyin fun ikú, nipa ìyan, ati nipa ongbẹ, o nwipe, Oluwa, Ọlọrun wa, yio gbà wa lọwọ ọba Assiria?

12. Kò ṣepe Hesekiah kanna li o mu ibi giga rẹ̀ wọnni kuro, ati pẹpẹ rẹ̀, ti o si paṣẹ fun Juda ati Jerusalemu, wipe, Ki ẹnyin ki o mã sìn niwaju pẹpẹ kan, ki ẹnyin ki o mã sun turari lori rẹ̀?

13. Enyin kò ha mọ̀ ohun ti emi ati awọn baba mi ti ṣe si gbogbo enia ilẹ miran? awọn oriṣa awọn orilẹ-ède ilẹ wọnni ha le gbà ilẹ wọn lọwọ mi rara?

14. Tani ninu gbogbo awọn oriṣa orilẹ-ède wọnni, ti awọn baba mi parun tũtu, ti o le gbà enia rẹ̀ lọwọ mi, ti Ọlọrun nyin yio fi le gbà nyin lọwọ mi?

15. Njẹ nitorina, ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah ki o tàn nyin jẹ, bẹ̃ni ki o máṣe rọ̀ nyin bi iru eyi, bẹ̃ni ki ẹ máṣe gbà a gbọ́: nitoriti kò si oriṣa orilẹ-ède tabi ijọba kan ti o le gbà enia rẹ̀ lọwọ mi, ati lọwọ awọn baba mi: ambọtori Ọlọrun nyin ti yio fi gbà nyin lọwọ mi?

16. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si sọ jù bẹ̃ lọ si Oluwa Ọlọrun, ati si iranṣẹ rẹ̀, Hesekiah.

17. O kọ iwe pẹlu lati kẹgan Oluwa, Ọlọrun Israeli, ati lati sọ̀rọ òdi si i, wipe, Gẹgẹ bi awọn oriṣa orilẹ-ède ilẹ miran kò ti gbà awọn enia wọn lọwọ mi, bẹ̃li Ọlọrun Hesekiah kì yio gbà awọn enia rẹ̀ lọwọ mi.

18. Nigbana ni nwọn kigbe li ohùn rara li ède Juda si awọn enia Jerusalemu ti mbẹ lori odi, lati dẹruba wọn, ati lati dãmu wọn; ki nwọn ki o le kó ilu na.

19. Nwọn si sọ̀rọ òdi si Ọlọrun Jerusalemu, bi ẹnipe si awọn oriṣa enia ilẹ aiye, ti iṣe iṣẹ ọwọ enia.

20. Ati nitori eyi ni Hesekiah, ọba, ati Isaiah woli, ọmọ Amosi, gbadura, nwọn si kigbe si ọrun.

21. Oluwa si rán Angeli kan, ẹniti o pa gbogbo awọn alagbara ogun, ati awọn aṣãju, ati awọn balogun ni ibudo ọba Assiria. Bẹ̃li o fi itiju pada si ilẹ on tikararẹ̀. Nigbati o si wá sinu ile oriṣa rẹ̀, awọn ti o ti inu ara rẹ̀ jade si fi idà pa a nibẹ.

22. Bayi li Oluwa gbà Hesekiah ati awọn ti ngbe Jerusalemu lọwọ Sennakeribu ọba Assiria, ati lọwọ gbogbo awọn omiran, o si ṣọ́ wọn ni iha gbogbo.

23. Ọ̀pọlọpọ si mu ẹ̀bun fun Oluwa wá si Jerusalemu, ati ọrẹ fun Hesekiah, ọba Juda: a si gbé e ga loju gbogbo orilẹ-ède lẹhin na.

24. Li ọjọ wọnni, Hesekiah ṣe aisan de oju ikú, o si gbadura si Oluwa; O si da a lohùn, O si fi àmi kan fun u.

25. Ṣugbọn Hesekiah kò si tun pada san gẹgẹ bi ore ti a ṣe fun u: nitoriti ọkàn rẹ̀ gbega: nitorina ni ibinu ṣe wà lori rẹ̀, lori Juda, ati lori Jerusalemu.

26. Ṣugbọn Hesekiah rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, niti igberaga ọkàn rẹ̀, ati on ati awọn ti ngbe Jerusalemu, bẹ̃ni ibinu Oluwa kò wá sori wọn li ọjọ Hesekiah.

Ka pipe ipin 2. Kro 32