Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 24:20-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ẹmi Ọlọrun si bà le Sakariah, ọmọ Jehoiada alufa, ti o duro ni ibi giga jù awọn enia lọ, o si wi fun wọn pe, Bayi li Ọlọrun wi pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ru ofin Oluwa, ẹnyin kì yio ri ire? nitoriti ẹnyin ti kọ̀ Oluwa silẹ, on pẹlu si ti kọ̀ nyin.

21. Nwọn si di rikiṣi si i, nwọn si sọ ọ li okuta nipa aṣẹ ọba li agbala ile Oluwa.

22. Bẹ̃ni Joaṣi, ọba, kò ranti õre ti Jehoiada, baba rẹ̀, ti ṣe fun u, o si pa ọmọ rẹ̀. Nigbati o si nkú lọ, o wipe, Ki Oluwa ki o wò o, ki o si bère rẹ̀.

23. O si ṣe li opin ọdun ni ogun Siria gòke tọ̀ ọ wá: nwọn si de Juda ati Jerusalemu, nwọn si pa gbogbo awọn ijoye enia run kuro ninu awọn enia na, nwọn si rán gbogbo ikógun wọn sọdọ ọba Damasku.

24. Nitori ogun awọn ara Siria dé pẹlu ẹgbẹ diẹ, Oluwa si fi ogun ti o pọ̀ gidigidi le wọn lọwọ, nitoriti nwọn kọ̀ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ. Bẹ̃ni nwọn si ṣe idajọ Joaṣi.

25. Nigbati nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀, (nwọn sa ti fi i silẹ ninu àrun nla) awọn iranṣẹ rẹ̀ si di rikiṣi si i, nitori ẹ̀jẹ awọn ọmọ Jehoiada alufa, nwọn si pa a lori akete rẹ̀, o si kú: nwọn si sìn i ni ilu Dafidi, ṣugbọn nwọn kò sìn i ni iboji awọn ọba.

26. Wọnyi li awọn ti o di rikiṣi si i, Sabadi, ọmọ Simeati, obinrin ara Ammoni, ati Jehosabadi, ọmọ Ṣimriti, obinrin ara Moabu.

27. Njẹ niti awọn ọmọ rẹ̀, ati titobi owo-ọba, ti a fi le e lori, ati atunṣe ile Ọlọrun, kiyesi i, a kọ wọn sinu itan iwe awọn ọba. Amasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 2. Kro 24