O si ṣe li opin ọdun ni ogun Siria gòke tọ̀ ọ wá: nwọn si de Juda ati Jerusalemu, nwọn si pa gbogbo awọn ijoye enia run kuro ninu awọn enia na, nwọn si rán gbogbo ikógun wọn sọdọ ọba Damasku.