Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 24:16-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Nwọn si sìn i ni ilu Dafidi pẹlu awọn ọba, nitoriti o ṣe rere ni Israeli, ati si Ọlọrun, ati si ile rẹ̀.

17. Lẹhin ikú Jehoiada awọn ijoye Juda de, nwọn si tẹriba fun ọba. Nigbana li ọba si gbọ́ ti wọn.

18. Nwọn si kọ̀ ile Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, nwọn si nsìn òriṣa ati ere: ibinu si wá sori Juda ati Jerusalemu nitori ẹ̀ṣẹ wọn yi.

19. Sibẹ o rán awọn woli si wọn, lati mu wọn pada tọ̀ Oluwa wá; nwọn si jẹri gbè wọn; ṣugbọn nwọn kò fi eti si i.

20. Ẹmi Ọlọrun si bà le Sakariah, ọmọ Jehoiada alufa, ti o duro ni ibi giga jù awọn enia lọ, o si wi fun wọn pe, Bayi li Ọlọrun wi pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ru ofin Oluwa, ẹnyin kì yio ri ire? nitoriti ẹnyin ti kọ̀ Oluwa silẹ, on pẹlu si ti kọ̀ nyin.

21. Nwọn si di rikiṣi si i, nwọn si sọ ọ li okuta nipa aṣẹ ọba li agbala ile Oluwa.

22. Bẹ̃ni Joaṣi, ọba, kò ranti õre ti Jehoiada, baba rẹ̀, ti ṣe fun u, o si pa ọmọ rẹ̀. Nigbati o si nkú lọ, o wipe, Ki Oluwa ki o wò o, ki o si bère rẹ̀.

23. O si ṣe li opin ọdun ni ogun Siria gòke tọ̀ ọ wá: nwọn si de Juda ati Jerusalemu, nwọn si pa gbogbo awọn ijoye enia run kuro ninu awọn enia na, nwọn si rán gbogbo ikógun wọn sọdọ ọba Damasku.

Ka pipe ipin 2. Kro 24