Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 23:11-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nigbana ni nwọn mu ọmọ ọba jade wá, nwọn si fi ade fun u ati iwe ẹri na, nwọn si fi i jọba: Jehoiada ati awọn ọmọ rẹ̀ si fi ororo yàn a, nwọn si wipe, Ki ọba ki o pẹ.

12. Nigbati Ataliah gbọ́ ariwo awọn enia, ti nwọn nsare lọ sibẹ, ti nwọn si nyìn ọba, o si tọ awọn enia na wá sinu ile Oluwa:

13. O si wò, si kiyesi i, ọba duro ni ibuduro rẹ̀ li ẹba ẹnu-ọ̀na, ati awọn balogun ati awọn afunpè lọdọ ọba: ati gbogbo awọn enia ilẹ na si yọ̀, nwọn si fun ipè, ati awọn akọrin pẹlu ohun-elo orin, ati awọn ti nkede lati kọ orin iyin. Nigbana ni Ataliah fa aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe: Ọ̀tẹ! Ọ̀tẹ!

14. Nigbana ni Jehoiada alufa mu awọn olori ọrọrun ani awọn olori ogun na jade, o si wi fun wọn pe, Ẹ mu u jade kuro ninu ile sẹhin àgbala: ẹni-kẹni ti o ba si tọ̀ ọ lẹhin, ni ki a fi idà pa. Nitori alufa wipe, Ẹ máṣe pa a ninu ile Oluwa.

15. Nwọn si fi àye fun u; nigbati o si de atiwọ̀ ẹnu-ọ̀na Ẹṣin ile ọba, nwọn si pa a nibẹ.

16. Jehoiada dá majẹmu lãrin on ati lãrin awọn enia, ati lãrin ọba pe, enia Oluwa li awọn o ma ṣe.

17. Gbogbo awọn enia na si lọ si ile Baali, nwọn si wó o lulẹ, nwọn si fọ pẹpẹ ati awọn ere rẹ̀ tũtu, nwọn si pa Mattani alufa Baali, niwaju pẹpẹ.

18. Jehoiada si fi iṣẹ itọju ile Oluwa le ọwọ awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, ti Dafidi ti pin lori ile Oluwa, lati ma ru ẹbọ ọrẹ sisun Oluwa, bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, pẹlu ayọ̀ ati pẹlu orin lati ọwọ Dafidi.

19. O si fi awọn adena si ẹnu-ọ̀na ile Oluwa, ki ẹni alaimọ́ ninu ohun-kohun ki o má ba wọ̀ ọ.

20. O si mu awọn olori-ọrọrun, ati awọn ọlọla, ati awọn bãlẹ ninu awọn enia ati gbogbo enia ilẹ na, nwọn si mu ọba sọ̀kalẹ lati ile Oluwa wá: nwọn si gbà ẹnu-ọ̀na giga wá sinu ile ọba, nwọn si gbé ọba ka ori itẹ ijọba na.

21. Gbogbo awọn enia ilẹ na si yọ̀: ilu na si tòro lẹhin ti a fi idà pa Ataliah.

Ka pipe ipin 2. Kro 23