Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 15:3-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Njẹ ọjọ pupọ ni Israeli ti wà laisìn Ọlọrun otitọ, ati laini alufa ti nkọni, ati laini ofin.

4. Ṣugbọn nwọn yipada si Oluwa. Ọlọrun Israeli, ninu wahala wọn, nwọn si ṣe awari rẹ̀, nwọn si ri i.

5. Ati li ọjọ wọnni alafia kò si fun ẹniti o njade, tabi fun ẹniti nwọle, ṣugbọn ibanujẹ pupọ li o wà lori gbogbo awọn olugbe ilẹ wọnni.

6. Orilẹ-ède si kọlù orilẹ-ède, ati ilu si ilu: nitori ti Ọlọrun fi oniruru ipọnju bà wọn ninu jẹ.

7. Ṣugbọn ẹnyin mu ara le, ki ẹ má si dẹ ọwọ nyin: nitori iṣẹ nyin yio ni ère.

8. Nigbati Asa gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, ati asọtẹlẹ Odedi woli, o mu ara le, o si mu awọn ohun irira kuro lati inu gbo-gbo ilẹ Juda ati Benjamini, ati lati inu ilu ti o ti gbà lati oke Efraimu, o si tun pẹpẹ Oluwa ṣe, ti o wà niwaju iloro Oluwa.

9. O si kó gbogbo Juda ati Benjamini jọ, ati awọn alejo ti o pẹlu wọn lati inu Efraimu ati Manasse, ati lati inu Simeoni wá: nitori ti nwọn ya li ọ̀pọlọpọ sọdọ rẹ̀ lati inu Israeli wá, nigbati nwọn ri pe, Oluwa Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀.

10. Bẹ̃ni nwọn kó ara wọn jọ si Jerusalemu, li oṣù kẹta, li ọdun kẹdogun ijọba Asa.

11. Nwọn si fi ninu ikógun ti nwọn kó wá, rubọ si Oluwa li ọjọ na, ẹ̃dẹgbãrin akọ-malu ati ẹ̃dẹgbãrin agutan.

12. Nwọn si tun dá majẹmu lati wá Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, tinutinu wọn ati tọkàntọkàn wọn.

13. Pe, ẹnikẹni ti kò ba wá Oluwa Ọlọrun Israeli, pipa li a o pa a, lati ẹni-kekere de ẹni-nla, ati ọkunrin ati obinrin.

Ka pipe ipin 2. Kro 15