Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 6:13-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Awọn ara Betṣemeṣi nkore alikama wọn li afonifoji: nwọn gbe oju wọn soke, nwọn si ri apoti na, nwọn si yọ̀ lati ri i.

14. Kẹkẹ́ na si wọ inu oko Joṣua, ara Betṣemeṣi, o si duro nibẹ, ibi ti okuta nla kan gbe wà: nwọn la igi kẹkẹ na, nwọn si fi malu wọnni ru ẹbọ sisun si Oluwa.

15. Awọn ọmọ Lefi si sọ apoti Oluwa na kalẹ, ati apoti ti o wà pẹlu rẹ̀, nibiti ohun elo wura wọnni gbe wà, nwọn si fi le ori okuta nla na: awọn ọkunrin Betṣemeṣi si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ si Oluwa li ọjọ na.

16. Nigbati awọn ijoye Filistini marun si ri i, nwọn tun yipada lọ si Ekroni li ọjọ kanna,

17. Wọnyi ni iyọdi wura ti awọn Filistini dá fun irubọ si Oluwa; ọkan ti Aṣdodu, ọkan ti Gasa, ọkan ti Aṣkeloni, ọkan ti Gati, ọkan ti Ekroni.

18. Ẹliri wura na si ri gẹgẹ bi iye gbogbo ilu awọn Filistini ti o jasi ti awọn ijoye marun na, ati ilu, ati ilu olodi, ati awọn ileto, titi o fi de ibi okuta nla Abeli, lori eyi ti nwọn gbe apoti Oluwa kà: okuta eyiti o wà titi di oni ninu oko Joṣua ara Betṣemeṣi.

19. On si pọn awọn ọkunrin Betṣemeṣi loju, nitoriti nwọn bẹ inu apoti Oluwa wò, iye wọn ti o pa ninu awọn enia na jẹ ẹgbã mẹdọgbọn o le ãdọrin ọkunrin, awọn enia na pohunrere ẹkun nitoriti Oluwa fi iparun nla pa ọpọ̀ awọn enia na run.

20. Awọn ọkunrin Betṣemeṣi si wipe, Tani yio le duro niwaju Oluwa Ọlọrun mimọ́ yi? ati lọdọ tani yio lọ bi o kuro lọdọ wa?

21. Nwọn ran awọn onṣẹ si awọn ara Kirjatjearimu wipe, Awọn Filistini mu apoti Oluwa wá; ẹ sọkalẹ wá, ki ẹ gbe e lọ sọdọ nyin.

Ka pipe ipin 1. Sam 6