Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 20:20-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Emi o si ta ọfà mẹta si ìha ibẹ̀ na, gẹgẹ bi ẹnipe mo ta si àmi kan.

21. Si wõ, emi o ran ọmọde-kọnrin kan pe, Lọ, ki o si wá ọfa wọnni. Bi emi ba tẹnu mọ ọ fun ọmọkunrin na, pe, Wõ, ọfa wọnni wà lẹhin rẹ, ṣà wọn wá; nigbana ni iwọ o ma bọ̀; nitoriti alafia mbẹ fun ọ, kò si ewu; bi Oluwa ti wà.

22. Ṣugbọn bi emi ba wi bayi fun ọmọde-kọnrin na pe, Wõ ọfa na mbẹ niwaju rẹ; njẹ ma ba tirẹ lọ; Oluwa li o rán ọ lọ.

23. Niti ọ̀rọ ti emi ati iwọ si ti jumọ sọ, wõ, ki Oluwa ki o wà larin iwọ ati emi titi lailai.

24. Bẹ̃ni Dafidi sì pa ara rẹ̀ mọ li oko; nigbati oṣu titun si de, ọba si joko lati jẹun.

25. Ọba si joko ni ipò rẹ̀ bi igba atijọ lori ijoko ti o gbe ogiri; Jonatani si dide, Abneri si joko ti Saulu, ipò Dafidi si ṣofo.

26. Ṣugbọn Saulu kò sọ nkan nijọ na; nitoriti on rò pe, Nkan ṣe e ni, on ṣe alaimọ́ ni; nitotọ o ṣe alaimọ́ ni.

27. O si ṣe, ni ijọ keji, ti o jẹ ijọ keji oṣu, ipò Dafidi si ṣofo; Saulu si wi fun Jonatani ọmọ rẹ̀ pe, Ẽṣe ti ọmọ Jesse ko fi wá si ibi onjẹ lana ati loni?

28. Jonatani si da Saulu lohùn pe, Dafidi bẹ̀ mi lati lọ si Betlehemu:

29. O si wipe, Jọwọ, jẹ ki emi ki o lọ; nitoripe idile wa li ẹbọ kan iru ni ilu na; ẹgbọn mi si paṣẹ fun mi pe ki emi ki o má ṣaiwà nibẹ; njẹ, bi emi ba ri oju rere gbà lọdọ rẹ, jọwọ, jẹ ki emi lọ, ki emi ri awọn ẹgbọn mi. Nitorina ni ko ṣe wá si ibi onjẹ ọba.

30. Ibinu Saulu si fà ru si Jonatani, o si wi fun u pe, Iwọ ọmọ ọlọtẹ buburu yi, ṣe emi mọ̀ pe, iwọ ti yàn ọmọ Jesse fun itiju rẹ, ati fun itiju ihoho iya rẹ?

31. Nitoripe ni gbogbo ọjọ ti ọmọ Jesse wà lãye li orilẹ, iwọ ati ijọba rẹ kì yio duro. Njẹ nisisiyi, ranṣẹ ki o si mu u fun mi wá, nitoripe yio kú dandan.

32. Jonatani si da Saulu baba rẹ̀ lohùn, o si wi fun u pe, Nitori kini on o ṣe kú? kili ohun ti o ṣe?

Ka pipe ipin 1. Sam 20