Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 17:12-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Dafidi si jẹ ọmọ ara Efrata na ti Betlehemu Juda, orukọ ẹniti ijẹ Jesse; o si ni ọmọ mẹjọ, o si jẹ arugbo larin enia li ọjọ Saulu.

13. Awọn mẹta ti o dàgba ninu awọn ọmọ Jesse, si tọ Saulu lẹhin lọ si oju ijà: orukọ awọn ọmọ mẹtẹta ti o lọ si ibi ijà si ni Eliabu, akọbi, atẹle rẹ̀ si ni Abinadabu, ẹkẹta si ni Ṣamma.

14. Dafidi si ni abikẹhin: awọn ẹgbọ́n iwaju rẹ̀ mẹtẹta ntọ̀ Saulu lẹhin.

15. Ṣugbọn Dafidi lọ, o si yipada lẹhin Saulu, lati ma tọju agutan baba rẹ̀ ni Betlehemu.

16. Filistini na a si ma sunmọ itosi li owurọ ati li alẹ, on si fi ara rẹ̀ han li ogoji ọjọ.

17. Jesse si wi fun Dafidi ọmọ rẹ̀ pe, Jọwọ, mu agbado didin yi ti ẹfa kan, ati iṣu akara mẹwa yi fun awọn ẹgbọn rẹ, ki o si sure tọ awọn ẹgbọn rẹ ni ibudo;

18. Ki o si mu warakasi mẹwa wọnyi fun oloriogun ẹgbẹrun wọn, ki o si wo bi awọn ẹgbọn rẹ ti nṣe, ki o si gbà nkan àmi wọn wá.

19. Saulu, ati awọn, ati gbogbo ọkunrin Israeli si wà ni afonifoji Ela, nwọn mba awọn Filistini jà.

20. Dafidi si dide ni kutukutu owurọ, o si fi agutan wọnni le olutọju kan lọwọ, o si mura, o si lọ, gẹgẹ bi Jesse ti fi aṣẹ fun u; on si de ibi yàra, ogun na si nlọ si oju ijà, nwọn hó iho ogun.

21. Israeli ati Filistini si tẹgun, ogun si pade ogun.

22. Dafidi si fi nkan ti o nmu lọ le ọkan ninu awọn olutọju nkan gbogbo lọwọ, o si sare si ogun, o tọ awọn ẹgbọn rẹ̀ lọ, o si ki wọn.

23. Bi on si ti mba wọn sọ̀rọ, sa wõ, akikanju ọkunrin na, Filistini ti Gati, ti orukọ rẹ̀ njẹ Goliati si goke wá, lati ogun awọn Filistini, o si sọ gẹgẹ bi ọ̀rọ ti o ti nsọ ri: Dafidi si gbọ́.

24. Gbogbo ọkunrin Israeli, nigbati nwọn si ri ọkunrin na, nwọn si sa niwaju rẹ̀, ẹ̀ru si ba wọn gidigidi.

25. Awọn ọkunrin Israeli si wipe, Ẹnyin kò ri ọkunrin yi ti o goke wá ihin? lati pe Israeli ni ijà li o ṣe wá: yio si ṣe pe, ẹniti o ba pa ọkunrin na, ọba yio si fi ọrọ̀ pipọ fun u, yio si fun u li ọmọ rẹ̀ obinrin, yio si sọ ile baba rẹ di omnira ni Israeli.

26. Dafidi si wi fun awọn ọkunrin ti o duro li ọdọ rẹ̀ pe, Kili a o ṣe fun ọkunrin na ti o ba pa Filistini yi, ti o si mu ẹgàn na kuro li ara Israeli? tali alaikọla Filistini yi iṣe, ti yio fi ma gan ogun Ọlọrun alãye?

27. Awọn enia na si da a li ohùn gẹgẹ bi ọ̀rọ yi pe, Bayi ni nwọn o ṣe fun ọkunrin ti o ba pa a.

28. Eliabu ẹgbọn rẹ̀ si gbọ́ nigbati on ba awọn ọkunrin na sọ̀rọ; Eliabu si binu si Dafidi, o si wipe, Ẽ ti ṣe ti iwọ fi sọkalẹ wá ihinyi, tani iwọ ha fi agutan diẹ nì le lọwọ́ li aginju? emi mọ̀ igberaga rẹ, ati buburu ọkàn rẹ; nitori lati ri ogun ni iwọ ṣe sọkalẹ wá.

Ka pipe ipin 1. Sam 17