Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 14:30-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. A! nitotọ, ibaṣepe awọn enia na ti jẹ ninu ikogun awọn ọta wọn ti nwọn ri, pipa awọn Filistini iba ti pọ to?

31. Nwọn pa ninu awọn Filistini li ọjọ na, lati Mikmaṣi de Aijaloni: o si rẹ̀ awọn enia na gidigidi.

32. Awọn enia sare si ikogun na, nwọn si mu agutan, ati malu, ati ọmọ-malu, nwọn si pa wọn sori ilẹ: awọn enia na si jẹ wọn t'ẹjẹ t'ẹjẹ.

33. Nigbana ni nwọn wi fun Saulu pe, kiye si i, awọn enia na dẹ̀ṣẹ si Oluwa, li eyi ti nwọn jẹ ẹjẹ. On si wipe, Ẹnyin ṣẹ̀ kọja: yi okuta nla fun mi wá loni.

34. Saulu si wipe, Ẹ tu ara nyin ka sarin awọn enia na ki ẹ si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ọkunrin mu malu tirẹ̀ tọ̀ mi wá, ati olukuluku ọkunrin agutan rẹ̀, ki ẹ si pa wọn nihin, ki ẹ si jẹ, ki ẹ má si ṣẹ̀ si Oluwa, ni jijẹ ẹjẹ. Gbogbo enia olukuluku ọkunrin mu malu rẹ̀ wá li alẹ na, nwọn si pa wọn ni ibẹ̀.

35. Saulu si tẹ pẹpẹ kan fun Oluwa; eyi ni pẹpẹ ti o kọ ṣe fun Oluwa.

36. Saulu wipe, Ẹ jẹ ki a sọkalẹ tọ̀ awọn Filistini lọ li oru, ki a ba wọn ja titi di imọlẹ owurọ̀, ẹ má jẹ ki a fi ọkunrin kan silẹ ninu wọn. Nwọn si wipe, Ṣe gbogbo eyi ti o tọ loju rẹ. Nigbana ni alufa ni si wipe, Ẹ jẹ ki a sunmọ ihinyi si Ọlọrun.

37. Saulu si bere lọdọ Ọlọrun pe, ki emi ki o sọkalẹ tọ̀ awọn Filistini lọ bi? Iwọ o fi wọn lé Israeli lọwọ́ bi? ṣugbọn kò da a lohùn li ọjọ na.

38. Saulu si wipe Mu gbogbo awọn àgba enia sunmọ ihinyi, ki ẹ mọ̀, ki ẹ si ri ibiti ẹ̀ṣẹ yi wà loni.

39. Nitoripe gẹgẹ bi Oluwa ti wà ti o ti gbà Israeli là bi o tilẹ ṣepe a ri i lara Jonatani ọmọ mi, nitõtọ yio kú. Ṣugbọn ninu gbogbo enia na, kò si ẹniti o da a lohùn.

40. Saulu si wi fun gbogbo awọn Israeli pe, Ẹnyin lọ si apakan, emi ati Jonatani ọmọ mi a si lọ si apakan. Gbogbo enia si wi fun Saulu pe, Ṣe eyi ti o tọ ni oju rẹ.

41. Saulu si wi fun Oluwa Ọlọrun Israeli pe, fun mi ni ibò ti o pé. A si mu Saulu ati Jonatani: ṣugbọn awọn enia na yege.

42. Saulu si wipe, Di ibò ti emi ati ti Jonatani ọmọ mi. Ibò na si mu Jonatani.

43. Saulu si wi fun Jonatani pe, Sọ nkan ti o ṣe fun mi. Jonatani si sọ fun u, o si wipe, Nitõtọ mo fi ori ọ̀pá ti mbẹ li ọwọ́ mi tọ́ oyin diẹ wò, wõ emi mura ati kú.

Ka pipe ipin 1. Sam 14