Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 14:11-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Awọn mejeji fi ara wọn hàn fun ogun Filistini: awọn Filistini si wipe, Wõ, awọn Heberu ti inu iho wọn jade wá, nibiti nwọn ti fi ara pamọ si.

12. Awọn ọkunrin ile olodi na si da Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ lohùn, nwọn si wipe, Goke tọ̀ wa wá, awa o si fi nkan hàn nyin; Jonatani si wi fun ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Ma tọ̀ mi lẹhìn; nitoripe Oluwa ti fi wọn le awọn enia Israeli lọwọ.

13. Jonatani rakò goke, ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ lẹhin rẹ̀; awọn Filistini si subu niwaju Jonatani; ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ npa lẹhin rẹ̀.

14. Pipa ikini, eyi ti Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ ṣe, o jasi iwọn ogún ọkunrin ninu abọ iṣẹko kan ti malu meji iba tú.

15. Ibẹ̀ru si wà ninu ogun na, ni pápá, ati ninu gbogbo awọn enia na; ile ọmọ-ogun olodi, ati awọn ti iko ikogun, awọn pẹlu bẹ̀ru; ilẹ sì mi: bẹ̃li o si jasi ọwáriri nlanla.

16. Awọn ọkunrin ti nṣọ́na fun Saulu ni Gibea ti Benjamini wò; nwọn si ri ọpọlọpọ awọn enia na tuka, nwọn si npa ara wọn bi nwọn ti nlọ.

17. Saulu si wi fun awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ pe, Njẹ ẹ kà awọn enia na ki ẹ si mọ̀ ẹniti o jade kuro ninu wa. Nwọn si kà, si kiye si i, Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ kò si si.

18. Saulu si wi fun Ahia pe, Gbe apoti Ọlọrun na wá nihinyi. Nitoripe apoti Ọlọrun wà lọdọ awọn ọmọ Israeli li akokò na.

19. O si ṣe, bi Saulu ti mba alufa na sọ̀rọ, ariwo ti o wà ni budo awọn Filistini si npọ̀ si i: Saulu si wi fun alufa na pe, dawọ́ duro.

20. Saulu ati gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀ ko ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá si oju ija: kiye si i, ida olukuluku si wà li ara ọmọnikeji rẹ̀, rudurudu na si pọ̀ gidigidi.

21. Pẹlupẹlu awọn Heberu ti o wà lọdọ awọn Filistini nigba atijọ, ti o si ti goke ba wọn lọ si budo lati ilu ti o wà yikakiri, awọn na pẹlu si yipada lati dapọ̀ mọ awọn Israeli ti o wà lọdọ Saulu ati Jonatani.

22. Bẹ̃ gẹgẹ nigbati gbogbo awọn ọkunrin Israeli ti o ti pa ara wọn mọ ninu okenla Efraimu gbọ́ pe awọn Filistini sa, awọn na pẹlu tẹle wọn lẹhin kikan ni ijà na.

23. Bẹ̃li Oluwa si gbà Israeli là lọjọ na: ija na si rekọja si Bet-afeni.

24. Awọn ọkunrin Israeli si ri ipọnju gidigidi ni ijọ na: nitoriti Saulu fi awọn enia na bu pe, Ifibu ni fun ẹniti o jẹ onjẹ titi di alẹ titi emi o si fi gbẹsan lara awọn ọta mi. Bẹ̃ni kò si ẹnikan ninu awọn enia na ti o fi ẹnu kan onjẹ.

Ka pipe ipin 1. Sam 14