Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 1:22-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Ṣugbọn Hanna ko goke lọ; nitori ti o wi fun ọkọ rẹ̀ pe, o di igbati mo ba gba ọmu lẹnu ọmọ na, nigbana li emi o mu u lọ, ki on ki o le fi ara han niwaju Oluwa, ki o si ma gbe ibẹ titi lai.

23. Elkana ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Ṣe eyi ti o tọ li oju rẹ; duro titi iwọ o fi gba ọmu li ẹnu rẹ̀; ṣugbọn ki Oluwa ki o sa mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ. Bẹ̃li obinrin na si joko, o si fi ọmu fun ọmọ rẹ̀ titi o fi gbà a lẹnu rẹ̀.

24. Nigbati o si gba ọmu li ẹnu rẹ̀, o si mu u goke lọ pẹlu ara rẹ̀, pẹlu ẹgbọrọ malu mẹta, ati iyẹfun efa kan, ati igo ọti-wain kan, o si mu u wá si ile Oluwa ni Ṣilo: ọmọ na si wà li ọmọde.

25. Nwọn pa ẹgbọrọ malu, nwọn si mu ọmọ na tọ̀ Eli wá.

26. Hanna si wipe, oluwa mi, bi ọkàn rẹ ti wà lãye, oluwa mi, emi li obinrin na ti o duro li ẹba ọdọ rẹ nihin ti ntọrọ lọdọ Oluwa.

27. Ọmọ yi ni mo ntọrọ; Oluwa si fi idahun ibere ti mo bere lọdọ rẹ̀ fun mi:

28. Nitorina pẹlu emi fi i fun Oluwa; ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀: nitoriti mo ti bere rẹ̀ fun Oluwa. Nwọn si wolẹ-sin Oluwa nibẹ.

Ka pipe ipin 1. Sam 1