Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 28:7-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Pẹlupẹlu emi o fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ lailai, bi o ba murale lati ṣe ofin mi ati idajọ mi bi li oni yi.

8. Njẹ nisisiyi li oju gbogbo Israeli ijọ enia Oluwa, ati li eti Ọlọrun wa, ẹ ma pamọ́ ki ẹ si ma ṣafẹri gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun nyin: ki ẹ le ni ilẹ rere yi, ki ẹ si le fi i silẹ li ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin lailai.

9. Ati iwọ, Solomoni ọmọ mi, mọ̀ Ọlọrun baba rẹ, ki o si fi aiya pipé ati fifẹ ọkàn sìn i: nitori Oluwa a ma wá gbogbo aiya, o si mọ̀ gbogbo ete ironu: bi iwọ ba ṣafẹri rẹ̀, iwọ o ri i; ṣugbọn bi iwọ ba kọ̀ ọ silẹ on o ta ọ nù titi lai.

10. Wò o nisisiyi: nitori Oluwa ti yàn ọ lati kọ́ ile kan fun ibi mimọ́, mura le, ki iwọ si ṣe e.

11. Nigbana ni Dafidi fi apẹrẹ fun Solomoni ọmọ rẹ̀ ti iloro, ati ti ile rẹ̀, ati ti ibi iṣura rẹ̀, ati ti iyara-òke rẹ̀, ati ti gbangan inu rẹ̀ ati ti ibi ibujoko ãnu,

12. Ati apẹrẹ gbogbo eyi ti o ni ni inu rẹ̀ pẹlu rẹ̀ niti agbala ile Oluwa, ati ti gbogbo iyara yikakiri, niti ibi iṣura ile Ọlọrun, ati niti ibi iṣura ohun ti a yà-si-mimọ́:

13. Niti ipin awọn alufa pẹlu ati ti awọn ọmọ Lefi, ati niti gbogbo iṣẹ ìsin ile Oluwa, ati niti gbogbo ohun èlo ìsin ni ile Oluwa.

14. Niti wura nipa ìwọn ti wura, niti gbogbo ohun èlo oniruru ìsin; niti gbogbo ohun èlo fadakà nipa ìwọn, niti gbogbo ohun èlo fun oniruru ìsin:

15. Ati ìwọn ọpa fitila wura, ati fitila wura wọn, nipa ìwọn fun olukuluku ọpa fitila ati ti fitila rẹ̀: ati niti ọpa fitila fadakà nipa ìwọn, ti olukuluku ọpa fitila ati ti fitila rẹ̀, gẹgẹ bi ìlo olukuluku ọpa fitila.

16. Ati wura nipa ìwọn fun tabili àkara ifihan, fun olukuluku tabili; ati fadakà fun tabili fadakà:

Ka pipe ipin 1. Kro 28