Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 22:12-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Kiki ki Oluwa ki o fun ọ li ọgbọ́n ati oye, ki o si fun ọ li aṣẹ niti Israeli, ki iwọ ki o le pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ́.

13. Nigbana ni iwọ o ma pọ̀ si i, bi iwọ ba ṣe akiyesi lati mu aṣẹ ati idajọ ti Oluwa pa fun Mose ṣẹ niti Israeli: mura giri ki o si ṣe onigboya, má bẹ̀ru bẹ̃ni ki aiya ki o máṣe fò ọ.

14. Si kiyesi i, ninu ipọnju mi, emi ti pèse fun ile Oluwa na, ọkẹ marun talenti wura, ati ẹgbẹrun ẹgbẹrun talenti fadakà; ati ti idẹ, ati ti irin, laini ìwọn; nitori ọ̀pọlọpọ ni: ati ìti-igi ati okuta ni mo ti pèse; iwọ si le wá kún u.

15. Pẹlupẹlu awọn oniṣẹ mbẹ fun ọ lọpọlọpọ, awọn gbẹnagbẹna ati awọn oniṣọna okuta ati igi ati onirũru ọlọgbọ́n enia fun onirũru iṣẹ.

16. Niti wura, fadakà ati idẹ, ati irin, kò ni ìwọn. Nitorina dide ki o si ma ṣiṣẹ, ki Oluwa ki o si pẹlu rẹ.

17. Dafidi paṣẹ pẹlu fun gbogbo awọn ijoye Israeli lati ran Solomoni ọmọ rẹ̀ lọwọ pe:

18. Oluwa Ọlọrun nyin kò ha wà pẹlu nyin? on kò ha ti fi isimi fun nyin niha gbogbo? on sa ti fi awọn ti ngbe ilẹ na le mi li ọwọ; a si ṣẹgun ilẹ na niwaju Oluwa ati niwaju enia rẹ̀.

19. Njẹ nisisiyi ẹ fi aiya nyin ati ọkàn nyin si atiwá Oluwa Ọlọrun nyin; nitorina dide ki ẹ si kọ́ ibi mimọ́ Oluwa Ọlọrun, lati mu apoti ẹri ti majẹmu Oluwa wọ̀ inu rẹ̀, ati ohun èlo mimọ́ Ọlọrun, sinu ile na ti a o kọ́ fun orukọ Oluwa.

Ka pipe ipin 1. Kro 22