Oluwa Ọlọrun nyin kò ha wà pẹlu nyin? on kò ha ti fi isimi fun nyin niha gbogbo? on sa ti fi awọn ti ngbe ilẹ na le mi li ọwọ; a si ṣẹgun ilẹ na niwaju Oluwa ati niwaju enia rẹ̀.