Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 22:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni Dafidi wipe, Eyi ni ile Oluwa Ọlọrun, eyi si ni pẹpẹ ọrẹ-sisun fun Israeli.

2. Dafidi si paṣẹ lati ko awọn alejo ti mbẹ ni ilẹ Israeli jọ; o si yan awọn agbẹkuta lati gbẹ okuta lati fi kọ́le Ọlọrun.

3. Dafidi si pese irin li ọ̀pọlọpọ fun iṣo fun ilẹkun ẹnu-ọ̀na, ati fun ìde; ati idẹ li ọ̀pọlọpọ li aini iwọn;

4. Igi kedari pẹlu li ainiye: nitori awọn ara Sidoni, ati awọn ti Tire mu ọ̀pọlọpọ igi kedari wá fun Dafidi.

5. Dafidi si wipe, Solomoni ọmọ mi, ọdọmọde ni, o si rọ̀, ile ti a o si kọ́ fun Oluwa, a o si ṣe e tobi jọjọ, fun okiki ati ogo ka gbogbo ilẹ: nitorina emi o pese silẹ fun u. Bẹ̃ni Dafidi si pese silẹ lọ̀pọlọpọ, ki o to kú.

6. Nigbana li o pe Solomoni ọmọ rẹ̀, o si fi aṣẹ fun u lati kọ́le kan fun Oluwa Ọlọrun Israeli.

7. Dafidi si wi fun Solomoni pe, Ọmọ mi, bi o ṣe ti emi ni, o ti wà li ọkàn mi lati kọ́le kan fun orukọ Oluwa Ọlọrun mi:

8. Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, Iwọ ti ta ẹ̀jẹ silẹ li ọ̀pọlọpọ, iwọ si ti ja ogun nlanla: iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun orukọ mi, nitoriti iwọ ta ẹ̀jẹ pipọ̀ silẹ niwaju mi.

Ka pipe ipin 1. Kro 22