Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 19:2-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Dafidi si wipe, Emi o ṣe ore fun Hanuni ọmọ Nahaṣi, nitoriti baba rẹ̀ ṣe ore fun mi. Dafidi si ran onṣẹ lati tù u ninu nitori baba rẹ̀. Bẹ̃ni awọn iranṣẹ Dafidi wá si ilẹ awọn ọmọ Ammoni, si ọdọ Hanuni lati tù u ninu.

3. Ṣugbọn awọn ijoye awọn ọmọ Ammoni wi fun Hanuni pe, Iwọ rò pe Dafidi bu ọlá fun baba rẹ nitori ti o ran awọn olutunu si ọ? Kò ṣepe awọn iranṣẹ rẹ̀ wá si ọdọ rẹ lati rin wò, ati lati bi ṣubu ati lati ṣe ami ilẹ na?

4. Nitorina Hanuni kó awọn iranṣẹ Dafidi, o si fa irungbọn wọn, o si ké agbáda wọn sunmọ ibadi wọn, o ran wọn lọ.

5. Nigbana ni awọn kan lọ, nwọn si sọ fun Dafidi bi a ti ṣe awọn ọkunrin na: on si ranṣẹ lọ ipade wọn: nitori oju tì awọn ọkunrin na gidigidi. Ọba si wipe, Ẹ duro ni Jeriko titi irungbọn nyin yio fi hù, nigbana ni ki ẹ si pada wá.

6. Nigbati awọn ọmọ Ammoni ri pe nwọn ti ba ara wọn jẹ lọdọ Dafidi, Hanuni ati awọn ọmọ Ammoni ran ẹgbẹrun talenti fadakà lati bẹ̀wẹ kẹkẹ́ ati ẹlẹsin lati Siria ni Mesopotamia wá, ati lati Siria-Maaka wá, ati lati Soba wá.

7. Bẹ̃ni nwọn bẹwẹ ẹgbã mẹrindilogun kẹkẹ́ ati ọba Maaka ati awọn enia rẹ̀; nwọn si wá nwọn si do niwaju Medeba. Awọn ọmọ Ammoni si ko ara wọn jọ lati ilu wọn, nwọn si wá si ogun.

8. Nigbati Dafidi gbọ́, o ran Joabu ati gbogbo ogun awọn akọni enia.

9. Awọn ọmọ Ammoni si jade wá, nwọn si tẹ ogun niwaju ẹnu-ibode ilu na: awọn ọba ti o wá si wà li ọtọ̀ ni igbẹ.

10. Nigbati Joabu ri pe a doju ija kọ on, niwaju ati lẹhin, o yàn ninu gbogbo ãyo Israeli, o si tẹ ogun wọn si awọn ara Siria.

11. O si fi iyokù awọn enia le Abiṣai arakunrin rẹ̀ lọwọ, nwọn si tẹ ogun si awọn ọmọ Ammoni.

12. On si wipe, Bi awọn ara Siria ba le jù fun mi, nigbana ni iwọ o ran mi lọwọ: ṣugbọn bi awọn ọmọ Ammoni ba le jù fun ọ, nigbana li emi o ràn ọ lọwọ.

13. Ṣe giri ki o si jẹ ki a huwa akọni fun enia wa ati fun ilu Ọlọrun wa: ki Oluwa ki o si ṣe eyi ti o dara loju rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. Kro 19