Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 19:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O SI ṣe lẹhin eyi, ni Nahaṣi ọba awọn ọmọ Ammoni kú, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2. Dafidi si wipe, Emi o ṣe ore fun Hanuni ọmọ Nahaṣi, nitoriti baba rẹ̀ ṣe ore fun mi. Dafidi si ran onṣẹ lati tù u ninu nitori baba rẹ̀. Bẹ̃ni awọn iranṣẹ Dafidi wá si ilẹ awọn ọmọ Ammoni, si ọdọ Hanuni lati tù u ninu.

3. Ṣugbọn awọn ijoye awọn ọmọ Ammoni wi fun Hanuni pe, Iwọ rò pe Dafidi bu ọlá fun baba rẹ nitori ti o ran awọn olutunu si ọ? Kò ṣepe awọn iranṣẹ rẹ̀ wá si ọdọ rẹ lati rin wò, ati lati bi ṣubu ati lati ṣe ami ilẹ na?

4. Nitorina Hanuni kó awọn iranṣẹ Dafidi, o si fa irungbọn wọn, o si ké agbáda wọn sunmọ ibadi wọn, o ran wọn lọ.

5. Nigbana ni awọn kan lọ, nwọn si sọ fun Dafidi bi a ti ṣe awọn ọkunrin na: on si ranṣẹ lọ ipade wọn: nitori oju tì awọn ọkunrin na gidigidi. Ọba si wipe, Ẹ duro ni Jeriko titi irungbọn nyin yio fi hù, nigbana ni ki ẹ si pada wá.

Ka pipe ipin 1. Kro 19