Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 8:41-58 Yorùbá Bibeli (YCE)

41. Pẹlupẹlu, niti alejò, ti kì iṣe ti inu Israeli enia rẹ, ṣugbọn ti o ti ilẹ okerè jade wá nitori orukọ rẹ.

42. Nitoriti nwọn o gbọ́ orukọ nla rẹ, ati ọwọ́ agbára rẹ, ati ninà apa rẹ; nigbati on o wá, ti yio si gbadura si iha ile yi;

43. Iwọ gbọ́ li ọrun, ibùgbe rẹ, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti alejò na yio ke pè ọ si: ki gbogbo aiye ki o lè mọ̀ orukọ rẹ, ki nwọn ki o lè mã bẹ̀ru rẹ, gẹgẹ bi Israeli, enia rẹ, ki nwọn ki o si lè mọ̀ pe: orukọ rẹ li a fi npè ile yi ti mo kọ́.

44. Bi enia rẹ ba jade lọ si ogun si ọtá wọn, li ọ̀na ti iwọ o rán wọn, bi nwọn ba si gbadura si Oluwa siha ilu ti iwọ ti yàn, ati siha ile ti mo kọ́ fun orukọ rẹ.

45. Nigbana ni ki o gbọ́ adura wọn, ati ẹ̀bẹ wọn li ọrun, ki o si mu ọràn wọn duro.

46. Bi nwọn ba ṣẹ̀ si ọ, nitoriti kò si enia kan ti kì iṣẹ̀, bi iwọ ba si binu si wọn, ti o si fi wọn le ọwọ́ ọta, tobẹ̃ ti a si kó wọn lọ ni igbèkun si ilẹ ọta, jijìna tabi nitosi;

47. Bi nwọn ba rò inu ara wọn wò ni ilẹ nibiti a gbe kó wọn ni igbèkun lọ, ti nwọn ba si ronupiwàda, ti nwọn ba si bẹ̀ ọ ni ilẹ awọn ti o kó wọn ni igbèkun lọ, wipe, Awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣe ohun ti kò tọ, awa ti ṣe buburu;

48. Bi nwọn ba si fi gbogbo àiya ati gbogbo ọkàn wọn yipada si ọ ni ilẹ awọn ọta wọn, ti o kó wọn ni igbèkun lọ, ti nwọn si gbadura si ọ siha ilẹ wọn, ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn, ilu ti iwọ ti yàn, ati ile ti emi kọ́ fun orukọ rẹ:

49. Nigbana ni ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn li ọrun ibugbe rẹ, ki o si mu ọ̀ran wọn duro:

50. Ki o si darijì awọn enia rẹ ti o ti dẹṣẹ si ọ, ati gbogbo irekọja wọn ninu eyiti nwọn ṣẹ̀ si ọ, ki o si fun wọn ni ãnu niwaju awọn ti o kó wọn ni igbèkun lọ, ki nwọn ki o le ṣãnu fun wọn.

51. Nitori enia rẹ ati ini rẹ ni nwọn, ti iwọ mu ti Egipti jade wá, lati inu ileru irin:

52. Ki oju rẹ ki o le ṣi si ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ, ati si ẹ̀bẹ Israeli enia rẹ, lati tẹtisilẹ si wọn ninu ohun gbogbo ti nwọn o ke pè ọ si.

53. Nitoriti iwọ ti yà wọn kuro ninu gbogbo orilẹ-ède aiye, lati mã jẹ ini rẹ, bi iwọ ti sọ lati ọwọ Mose iranṣẹ rẹ, nigbati iwọ mu awọn baba wa ti Egipti jade wá, Oluwa Ọlọrun.

54. O si ṣe, bi Solomoni ti pari gbigbà gbogbo adura ati ẹ̀bẹ yi si Oluwa, o dide kuro lori ikunlẹ ni ẽkún rẹ̀ niwaju pẹpẹ Oluwa pẹlu titẹ́ ọwọ rẹ̀ si oke ọrun.

55. O si dide duro, o si fi ohùn rara sure fun gbogbo ijọ enia Israeli wipe,

56. Ibukún ni fun Oluwa ti o ti fi isimi fun Israeli enia rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ti ṣe ileri: kò kù ọ̀rọ kan ninu gbogbo ileri rere rẹ̀ ti o ti ṣe lati ọwọ Mose, iranṣẹ rẹ̀ wá.

57. Oluwa Ọlọrun wa ki o wà pẹlu wa, bi o ti wà pẹlu awọn baba wa: ki o má fi wa silẹ, ki o má si ṣe kọ̀ wa silẹ;

58. Ṣugbọn ki o fa ọkàn wa si ọdọ ara rẹ̀, lati ma rin ninu gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ti o ti paṣẹ fun awọn baba wa.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 8