Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 7:20-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ati awọn ipari lori ọwọ̀n meji na wà loke: nwọn si sunmọ ibi ti o yọ lara ọwọ̀n ti o wà nibi iṣẹ àwọn: awọn pomegranate jẹ igba ni ọ̀wọ́ yikakiri, lori ipari keji.

21. O si gbe awọn ọwọ̀n na ro ni iloro tempili: o si gbe ọwọ̀n ọ̀tun ró, o si pe orukọ rẹ̀ ni Jakini: o si gbe ọwọ̀n òsi ró, o si pe orukọ rẹ̀ ni Boasi.

22. Lori oke awọn ọwọ̀n na ni iṣẹ lili wà; bẽni iṣẹ ti awọn ọwọ̀n si pari.

23. O si ṣe agbada nla didà igbọnwọ mẹwa lati eti kan de ekeji: o ṣe birikiti, giga rẹ̀ si jẹ igbọnwọ marun: okùn ọgbọ̀n igbọnwọ li o si yi i kakiri.

24. Ati nisalẹ eti rẹ̀ yikakiri kóko wà yi i ka, mẹwa ninu igbọnwọ kan, o yi agbada nla na kakiri: a dà kóko na ni ẹsẹ meji, nigbati a dà a.

25. O duro lori malu mejila, mẹta nwo iha ariwa, mẹta si nwo iwọ-õrun, mẹ̃ta si nwo gusu, mẹta si nwo ila-õrun; agbada nla na si joko lori wọn, gbogbo apa ẹhin wọn si mbẹ ninu.

26. O si nipọn to ibú atẹlẹwọ, a si fi itanna lili ṣiṣẹ eti rẹ̀ gẹgẹ bi eti ago, o si gbà ẹgbã iwọ̀n Bati.

27. O si ṣe ijoko idẹ mẹwa; igbọnwọ mẹrin ni gigùn ijoko kọkan, igbọnwọ mẹrin si ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ mẹta ni giga rẹ̀.

28. Iṣẹ awọn ijoko na ri bayi: nwọn ni alafo ọ̀na arin, alafo ọ̀na arin na si wà lagbedemeji ipade eti.

29. Ati lara alafo ọ̀na arin ti mbẹ lagbedemeji ni aworan kiniun, malu, ati awọn kerubu wà; ati lori ipade eti, ijoko kan wà loke: ati labẹ awọn kiniun, ati malu ni iṣẹ ọṣọ́ wà.

30. Olukuluku ijoko li o ni ayika kẹkẹ́ idẹ mẹrin, ati ọpa kẹkẹ́ idẹ: igun mẹrẹrin rẹ̀ li o ni ifẹsẹtẹ labẹ; labẹ agbada na ni ifẹsẹtẹ didà wà, ni iha gbogbo iṣẹ ọṣọ́ na.

31. Ẹnu rẹ̀ ninu ipari na ati loke jẹ igbọnwọ kan: ṣugbọn ẹnu rẹ̀ yika gẹgẹ bi iṣẹ ijoko na, si jẹ igbọnwọ kan on àbọ: ati li ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbigbẹ́ wà pẹlu alafo ọ̀na arin wọn, nwọn si dọgba ni igun mẹrẹrin, nwọn kò yika.

32. Ati nisalẹ alafo ọ̀na arin, ayika-kẹkẹ́ mẹrin li o wà: a si so ọpa ayika-kẹkẹ́ na mọ ijoko na; giga ayika-kẹkẹ́ kan si jẹ igbọnwọ kan pẹlu àbọ.

33. Iṣẹ ayika-kẹkẹ́ na si dabi iṣẹ kẹkẹ́; igi idalu wọn, ati ibi iho, ati ibi ipade, ati abukala wọn, didà ni gbogbo wọn.

34. Ifẹsẹtẹ mẹrin li o wà fun igun mẹrin ijoko na: ifẹsẹtẹ na si jẹ ti ijoko tikararẹ̀ papã.

35. Ati loke ijoko na, ayika kan wà ti àbọ igbọnwọ: ati loke ijoko na ẹgbẹgbẹti rẹ̀ ati alafo ọ̀na arin rẹ̀ jẹ bakanna.

36. Ati lara iha ẹgbẹti rẹ̀, ati leti rẹ̀, li o gbẹ́ aworan kerubu, kiniun, ati igi-ọpẹ gẹgẹ bi aye olukuluku, ati iṣẹ ọṣọ yikakiri.

37. Gẹgẹ bayi li o si ṣe awọn ijoko mẹwẹwa: gbogbo wọn li o si ni didà kanna, iwọ̀n kanna ati titobi kanna.

38. O si ṣe agbada idẹ mẹwa: agbada kan gbà to òji iwọn Bati: agbada kọ̃kan si jẹ igbọnwọ mẹrin: lori ọkọ̃kan ijoko mẹwẹwa na ni agbada kọ̃kan wà.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 7