Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 18:8-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. O si da a lohùn pe, Emi ni: lọ, sọ fun oluwa rẹ pe, Wò o, Elijah mbẹ nihin.

9. On si wipe, Ẹ̀ṣẹ kini mo ha dá, ti iwọ fẹ fi iranṣẹ rẹ le Ahabu lọwọ lati pa mi?

10. Bi Oluwa Ọlọrun rẹ ti wà, kò si orilẹ-ède tabi ijọba kan, nibiti oluwa mi kò ranṣẹ de lati wò ọ: nigbati nwọn ba si wipe, Kò si; on a mu ki ijọba tabi orilẹ-ède na bura pe: awọn kò ri ọ.

11. Nisisiyi iwọ si wipe, Lọ, sọ fun oluwa rẹ pe, Wò o, Elijah mbẹ nihin;

12. Yio si ṣe bi emi o ti lọ kuro li ọdọ rẹ, Ẹmi Oluwa yio si gbe ọ lọ si ibi ti emi kò mọ̀; nigbati mo ba si de, ti mo si wi fun Ahabu, ti kò ba si ri ọ, on o pa mi: ṣugbọn emi, iranṣẹ rẹ, bẹ̀ru Oluwa lati igba ewe mi wá.

13. A kò ha sọ fun oluwa mi, ohun ti mo ṣe nigbati Jesebeli pa awọn woli Oluwa, bi mo ti pa ọgọrun enia mọ ninu awọn woli Oluwa li aradọta ninu ihò-okuta, ti mo si fi àkara pẹlu omi bọ́ wọn?

14. Nisisiyi, iwọ si wipe, Lọ sọ fun oluwa rẹ pe, Wò o, Elijah mbẹ nihin! on o si pa mi.

15. Elijah si wipe, Bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, nitõtọ, emi o fi ara mi han fun u loni yi.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 18