Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 13:24-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Nigbati o si lọ tan, kiniun kan pade rẹ̀ li ọ̀na, o si pa a: a si gbe okú rẹ̀ sọ si oju ọ̀na, kẹtẹkẹtẹ si duro tì i, kiniun pẹlu duro tì okú na.

25. Si kiyesi i, awọn enia nkọja, nwọn ri pe, a gbe okú na sọ si oju ọ̀na, kiniun na si duro tì okú na: nwọn si wá, nwọn si sọ ọ ni ilu ti woli àgba na ngbe.

26. Nigbati woli ti o mu u lati ọ̀na pada bọ̀ gbọ́, o wipe, Enia Ọlọrun na ni, ti o ṣọ̀tẹ si Oluwa: nitorina li Oluwa fi i le kiniun lọwọ, ti o si fà a ya, ti o si pa a, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti sọ fun u.

27. O si wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun mi. Nwọn si di i ni gari.

28. O si lọ, o si ri, a gbé okú rẹ̀ sọ si oju ọ̀na, ati kẹtẹkẹtẹ, ati kiniun duro ti okú na, kiniun kò jẹ okú na, bẹ̃ni kò fà kẹtẹkẹtẹ na ya.

29. Woli na mu okú enia Ọlọrun na, o si gbé e lori kẹtẹkẹtẹ na, o si mu u pada bọ̀: woli àgba na si wá si ilu, lati ṣọ̀fọ, ati lati sin i.

30. O si tẹ okú rẹ̀ sinu iboji ara rẹ̀: nwọn si sọ̀fọ lori rẹ̀, pe: O ṣe, arakunrin mi!

31. O si ṣe, lẹhin igbati o ti sinkú rẹ̀ tan, o si sọ fun awọn ọmọ rẹ̀ wipe, Nigbati mo ba kú, nigbana ni ki ẹ sinkú mi ni iboji ninu eyiti a sin enia Ọlọrun; ẹ tẹ́ egungun mi lẹba egungun rẹ̀:

32. Nitori ni ṣiṣẹ, ọ̀rọ ti o kigbe nipa ọ̀rọ Oluwa si pẹpẹ na ni Beteli, ati si gbogbo ile ibi giga ti mbẹ ni gbogbo ilu Samaria, yio ṣẹ dandan.

33. Lẹhin nkan yi, Jeroboamu kò pada kuro ninu ọ̀na ibi rẹ̀, ṣugbọn o tun mu ninu awọn enia ṣe alufa ibi giga wọnni: ẹnikẹni ti o ba fẹ, a yà a sọtọ̀ on a si di alufa ibi giga wọnni.

34. Nkan yi si di ẹ̀ṣẹ ile Jeroboamu, ani lati ke e kuro, ati lati pa a run kuro lori ilẹ.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 13