1. SI kiyesi i, enia Ọlọrun kan lati Juda wá si Beteli nipa ọ̀rọ Oluwa: Jeroboamu duro lẹba pẹpẹ lati fi turari jona.
2. O si kigbe si pẹpẹ na nipa ọ̀rọ Oluwa, o si wipe, Pẹpẹ! pẹpẹ! bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, a o bi ọmọ kan ni ile Dafidi, Josiah li orukọ rẹ̀; lori rẹ ni yio si fi awọn alufa ibi giga wọnni ti nfi turari jona lori rẹ rubọ, a o si sun egungun enia lori rẹ.
3. O si fun wọn li àmi kan li ọjọ kanna wipe, Eyi li àmi ti Oluwa ti ṣe; Kiyesi i, pẹpẹ na yio ya, ẽru ti mbẹ lori rẹ̀ yio si danu.
4. O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọba gbọ́ ọ̀rọ enia Ọlọrun, ti o ti kigbe si pẹpẹ na, o wipe, Ẹ mu u. Ọwọ́ rẹ̀ ti o nà si i, si gbẹ, bẹ̃ni kò si le fa a pada sọdọ rẹ̀ mọ.
5. Pẹpẹ na si ya, ẽru na si danù kuro ninu pẹpẹ na, gẹgẹ bi àmi ti enia Ọlọrun ti fi fun u nipa ọ̀rọ Oluwa.
6. Ọba si dahùn, o si wi fun enia Ọlọrun na pe, Tù Oluwa Ọlọrun rẹ loju nisisiyi, ki o si gbadura fun mi, ki a ba le tun mu ọwọ́ mi bọ̀ sipo fun mi. Enia Ọlọrun na si tù Ọlọrun loju, a si tun mu ọwọ́ ọba bọ̀ sipo fun u, o si dàbi o ti wà ri.
7. Ọba si wi fun enia Ọlọrun na pe, Wá ba mi lọ ile, ki o si tù ara rẹ lara, emi o si ta ọ li ọrẹ.