Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esr 7:18-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ati ohunkohun ti o ba wu ọ, ati awọn arakunrin rẹ lati fi fàdaka ati wura iyokù ṣe, eyini ni ki ẹnyin ki o ṣe gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun nyin.

19. Ohun-èlo wọnni ti a fi fun ọ pẹlu fun ìsin ile Ọlọrun rẹ, ni ki iwọ ki o fi lelẹ niwaju Ọlọrun ni Jerusalemu.

20. Ati ohunkohun ti a ba fẹ pẹlu fun ile Ọlọrun rẹ, ti iwọ o ri àye lati nawo rẹ̀, nawo rẹ̀ lati inu ile iṣura ọba wá.

21. Ati emi, ani Artasasta ọba paṣẹ fun gbogbo awọn olutọju iṣura, ti o wà li oke odò pe, ohunkohun ti Esra alufa, ti iṣe akọwe ofin Ọlọrun ọrun yio bère lọwọ nyin, ki a ṣe e li aijafara,

22. Titi de ọgọrun talenti fàdaka, ati de ọgọrun oṣuwọn alikama, ati de ọgọrun bati ọti-waini, ati de ọgọrun bati ororo, ati iyọ laini iye.

23. Ohunkohun ti Ọlọrun ọrun palaṣẹ, ki a fi otitọ ṣe e fun ile Ọlọrun ọrun: ki ibinu ki o má de si ijọba ọba, ati awọn ọmọ rẹ̀.

24. Pẹlupẹlu ki ẹnyin ki o mọ̀ dajudaju pe, ẹnyin kò ni oyè lati di owo-ori, owo-odè, ati owo-bodè ru gbogbo awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, awọn akọrin, awọn adèna, awọn Netinimu, ati awọn iranṣẹ ninu ile Ọlọrun yi,

25. Ati iwọ, Esra, gẹgẹ bi ọgbọ́n Ọlọrun rẹ ti o wà li ọwọ rẹ, yan awọn oloyè ati onidajọ, ti nwọn o ma da ẹjọ fun gbogbo awọn enia ti o wà li oke-odò, gbogbo iru awọn ti o mọ̀ ofin Ọlọrun rẹ, ki ẹnyin ki o si ma kọ́ awọn ti kò mọ̀ wọn.

26. Ẹnikẹni ti kì o si ṣe ofin Ọlọrun rẹ, ati ofin ọba, ki a mu idajọ ṣe si i lara li aijafara, bi o ṣe si ikú ni, tabi lilé si oko, tabi kiko li ẹrù, tabi si sisọ sinu tubu.

27. Olubukun li Oluwa Ọlọrun awọn baba wa, ti o fi nkan bi iru eyi si ọkàn ọba, lati ṣe ogo si ile Oluwa ti o wà ni Jerusalemu:

28. Ti o si nàwọ anu si mi niwaju ọba ati awọn ìgbimọ rẹ̀, ati niwaju gbogbo awọn alagbara ijoye ọba: mo si ri iranlọwọ gbà gẹgẹ bi ọwọ Oluwa Ọlọrun mi ti o wà lara mi, mo si ko awọn olori awọn enia jọ lati inu Israeli jade, lati ba mi goke lọ.

Ka pipe ipin Esr 7