Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 43:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Wọnyi si ni iwọ̀n pẹpẹ nipa igbọnwọ; Igbọnwọ jẹ igbọnwọ kan ati ibú atẹlẹwọ kan; isalẹ rẹ̀ yio jẹ igbọnwọ kan, ati ibu rẹ̀ igbọnwọ kan, ati igbati rẹ̀ ni eti rẹ̀ yika yio jẹ ika kan: eyi ni yio si jẹ ibi giga pẹpẹ na.

14. Lati isalẹ ilẹ titi de ijoko isalẹ yio jẹ igbọnwọ meji, ati ibú rẹ̀ igbọnwọ́ kan; ati lati ijoko kekere titi de ijoko nla yio jẹ igbọnwọ mẹrin, ati ibú rẹ̀ igbọnwọ kan.

15. Pẹpẹ na si jẹ igbọnwọ mẹrin: ati lati pẹpẹ titi de oke jẹ iwo mẹrin.

16. Pẹpẹ na yio si jẹ igbọnwọ mejila ni gigùn, ati mejila ni ibú onigun mẹrin ni igun mẹrẹrin rẹ̀.

17. Ati ijoko ni yio jẹ igbọ̀nwọ mẹrinla ni gigun ati mẹrinla ni ibú ninu igun mẹrẹrin rẹ̀; ati eti rẹ̀ yika yio jẹ́ abọ̀ igbọnwọ; ati isalẹ rẹ̀ yio jẹ igbọnwọ kan yika; atẹgùn rẹ̀ yio si kọjusi iha ila-õrun.

18. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Eyi ni aṣẹ pẹpẹ na li ọjọ ti nwọn o ṣe e, lati rú ọrẹ ẹbọ sisun lori rẹ̀, ati lati wọ́n ẹ̀jẹ sori rẹ̀.

19. Iwọ o si fi ẹgbọrọ malu, fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, fun awọn alufa, awọn Lefi, ti iṣe iru-ọmọ Sadoku, ti nsunmọ mi, lati ṣe iranṣẹ fun mi, ni Oluwa Ọlọrun wi.

20. Iwọ o si mu ninu ẹjẹ rẹ̀, iwọ o si fi si iwo mẹrẹrin rẹ̀, ati si igun mẹrẹrin ijoko na, ati si eti rẹ̀ yika: iwọ o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ mọ́, iwọ o si ṣe etùtu rẹ̀.

21. Iwọ o si mu ẹgbọrọ malu ti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, on o si sun u ni ibiti a yàn ni ile na lode ibi-mimọ́.

22. Ati ni ọjọ keji iwọ o fi ọmọ ewurẹ alailabawọn rubọ ọrẹ ẹ̀ṣẹ; nwọn o si sọ pẹpẹ na di mimọ́, bi nwọn iti ifi ẹgbọrọ malu sọ ọ di mimọ́.

23. Nigbati iwọ ba ti sọ ọ di mimọ tan, iwọ o fi ẹgbọrọ malu alailabawọn rubọ, ati àgbo alailabawọn lati inu agbo wá.

Ka pipe ipin Esek 43