9. O si wọ̀n iloro ẹnu-ọ̀na, igbọnwọ mẹjọ; ati atẹrigba rẹ̀, igbọnwọ meji-meji; iloro ti ẹnu-ọ̀na na si mbẹ ninu.
10. Ati yará kékèké ẹnu-ọ̀na ti ọ̀na ila-õrun jẹ mẹta nihà ìhin, ati mẹta nihà ọhún; awọn mẹtẹta jẹ ìwọn kanna: awọn atẹrigba na jẹ ìwọn kanna niha ìhin ati niha ọhún.
11. O si wọ̀n ibu abawọle ẹnu-ọ̀na na, igbọnwọ mẹwa; ati gigùn ẹnu-ọ̀na na, igbọnwọ mẹtala.
12. Àye ti si mbẹ niwaju awọn yará kékèké na jẹ igbọnwọ kan nihà ìhin, àye na si jẹ igbọnwọ kan nihá ọhún; awọn yará kékèké na si jẹ igbọnwọ mẹfa nihà ìhin, ati igbọnwọ mẹfa niha ọhún.
13. O si wọ̀n ẹnu-ọ̀na na lati orule yará kékèké kan lọ de orule miran: ibú rẹ jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọn, ilẹkùn dojukọ ilẹkùn.
14. O si ṣe atẹrigba ọlọgọta igbọnwọ, ani titi de atẹrigba àgbalá yi ẹnu-ọ̀na na ka.
15. Lati iwaju ẹnu-ọ̀na àtẹwọ titi fi de iwaju iloro ẹnu-ọ̀na ti inu, adọta igbọnwọ.
16. Awọn ferese tõro si mbẹ lara yará kékèké na, ati lara atẹrigba wọn ninu ẹnu-ọ̀na niha gbogbo ati pẹlu yará iloro: ferese pupọ si mbẹ niha inu gbogbo: igi ọpẹ si mbẹ lara olukuluku atẹrigbà.
17. O si mu mi wá si agbala ode, si kiyesi i, ọ̀pọlọpọ yará mbẹ nibẹ, a si fi okuta tẹ́ agbala na niha gbogbo: ọgbọ̀n yará ni mbẹ lori okuta itẹlẹ na.
18. Ati okuta itẹlẹ ti iha ẹnu-ọ̀na na ti o kọju si gigun ẹnu-ọ̀na, ani okuta itẹlẹ isalẹ.
19. O si wọ̀n ibú rẹ̀ lati iwaju ẹnu-ọ̀na isalẹ titi fi de iwaju àgbala inu ti ode, ọgọrun igbọnwọ niha ila-õrun ati niha ariwa.
20. Ẹnu-ọ̀na àgbala ode ti o kọju si ariwa, o wọ̀n gigun rẹ̀, ati ibu rẹ̀.