Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 33:10-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọ fun ile Israeli; pe, Bayi li ẹnyin nwi, pe, Bi irekọja ati ẹ̀ṣẹ wa ba wà lori wa, ti awa si njoró ninu wọn, bawo li a o ti ṣe le wà lãye.

11. Sọ fun wọn pe, Bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, emi kò ni inu-didun ni ikú enia buburu, ṣugbọn ki enia buburu yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀ ki o si yè: ẹ yipada, ẹ yipada kuro ninu ọ̀na buburu nyin; nitori kini ẹnyin o ṣe kú, Ile Israeli?

12. Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọ fun awọn ọmọ enia rẹ, ododo olododo kì yio gbà a là li ọjọ irekọja rẹ̀: bi o ṣe ti ìwa buburu enia buburu, on kì yio ti ipa rẹ̀ ṣubu li ọjọ ti o yipada kuro ninu ìwa buburu rẹ̀: bẹ̃ni olododo kì yio là nipa ododo rẹ̀ li ọjọ ti o dẹṣẹ.

13. Nigbati emi o wi fun olododo pe, yiyè ni yio yè, bi o ba gbẹkẹle ododo ara rẹ̀, ti o si ṣe aiṣedẽde, gbogbo ododo rẹ̀ li a kì yio ranti mọ, ṣugbọn nitori aiṣedẽde ti o ti ṣe, on o ti itori rẹ̀ kú.

14. Ẹ̀wẹ, nigbati emi wi fun enia buburu pe, Kikú ni iwọ o kú; bi on ba yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o si ṣe eyi ti o tọ ti o si yẹ;

15. Bi enia buburu ba mu ògo padà, ti o si san ohun ti o ti jí padà, ti o si nrin ni ilana ìye, li aiṣe aiṣedẽde; yiyè ni yio yè, on kì o kú.

16. A kì yio ṣe iranti gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ndá fun u: on ti ṣe eyi ti o tọ ti o si yẹ; on o yè nitõtọ.

17. Sibẹ awọn ọmọ enia rẹ wipe, Ọ̀na Oluwa kò dọgba: ṣugbọn bi o ṣe ti wọn ni, ọ̀na wọn kò dọgba.

18. Nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀ ti o si ṣe aiṣedẽde, on o ti ipa rẹ̀ kú.

19. Ṣugbọn bi enia buburu bá yipada kuro ninu buburu rẹ̀, ti o si ṣe eyiti o tọ ti o si yẹ̀, on o ti ipa rẹ̀ wà lãye.

20. Sibẹ ẹnyin wi pe, Ọ̀na Oluwa kò dọgba, Ẹnyin ile Israeli, emi o dá olukuluku nyin li ẹjọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀.

21. O si ṣe li ọdun ikejila ikolọ wa, li oṣu kẹwa, li ọjọ karun oṣu, ẹnikan ti o ti salà jade ni Jerusalemu tọ̀ mi wá, o wipe, A kọlù ilu na.

22. Ọwọ́ Oluwa si wà lara mi li àṣalẹ, ki ẹniti o salà na to de; o si ti ṣi ẹnu mi, titi on fi wá sọdọ mi li owurọ; ẹnu mi si ṣi, emi kò si yadi mọ.

Ka pipe ipin Esek 33